Jọkẹ Amọri
Ile-ẹjọ giga kan ni ilu Abuja, labẹ aṣẹ Onidaajọ Inyang Ekwo, ti paṣẹ pe ki Gomina ipinlẹ Ebonyi, Dave Umahi ati Igbakeji rẹ, Eric Kelechi Igwe, fipo wọn silẹ, ki ajọ INEC si ṣeto ki ẹgbẹ PDP yan ẹlomi-in lati pari saa wọn tabi ki wọn ṣeto idibo mi-in.
Igbesẹ yii waye latari bi awọn mejeeji ṣe fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ, ti wọn si darapọ mọ ẹgbẹ APC, lai si idi pataki kan labẹ ofin lati fi ṣe bẹẹ.
Ninu idajọ to waye nile-ẹjọ giga naa ni Ekwo ti sọ pe pẹlu bi wọn ṣe kuro ninu ẹgbẹ ti wọn ti dije dupo, ti wọn si wọle, niṣe lo yẹ ki wọn kọwe fipo silẹ ti wọn ba mọ pe awọn fẹẹ lọ si ẹgbẹ oṣelu mi-in. Niwọn igba ti ki i si i ti i ṣe pe wahala kankan ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa to le mu ki igbesẹ ti wọn gbe yii waye, dandan ni ki wọn fi ipo gomina ati igbakeji ti wọn wa silẹ.
Adajọ waa paṣẹ fun ajọ eleto idibo nilẹ wa (INEC), pe ki wọn tẹwọ gba awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ti wọn ba fẹẹ fi rọpo awọn ti wọn le kuro nibẹ yii lati lo ọjọ yooku to yẹ ki wọn lo nipo, tabi ki wọn ṣeto idibo mi-in lati yan awọn mi-in ti yoo dipo awọn ti wọn yọ yii.