Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọmọ ileewe kan ti pade iku ojiji nigba tawọn meji tun fara gbọta, nibi ti wọn ti n ṣere idaraya olojule sojule laarin awọn akẹkọọ ileewe girama Agolo, to wa niluu Ikarẹ Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ ta a wa yii.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, pẹlu ayọ ati idunnu ni wọn fi bẹrẹ eto idije naa lọsan-an ọjọ ta a n sọrọ rẹ yii, ti ọgọọrọ awọn akẹkọọ ti wọn fi iwe pe kaakiri awọn ileewe to wa lagbegbe Akoko atawọn oluworan si ti wa ni ikalẹ lati kopa ninu eto ayẹyẹ ọlọdọọdun naa.
Lojiji lawọn eeyan bẹrẹ si i gbọ iro ibọn to n dun lakọlakọ, leyii to mu kawọn to wa nibẹ maa sa kijokijo, ti olukuluku si n gbiyanju lati sa asala fun ẹmi rẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko le sọ pato apa ibi ti iro ibọn ọhun ti n wa.
Akẹkọọ mẹta ni wọn lo fara gbọta lasiko rogbodiyan ọhun, ti ọkan si ku loju-ẹsẹ, nigba tawọn meji yooku wa nileewosan kan ti wọn ti n gba itọju lọwọ.
Bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ ta a n sọrọ rẹ ọhun da jinnijinni bo awọn araalu Ikarẹ Akoko ati agbegbe rẹ, sibẹ, ọpọ awọn obi gbe iku ta lẹyin ti wọn gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun, ti olukuluku wọn si mori le ileewe naa lati wa eeyan wọn lọ.
Ko sẹni to ti i le sọ ni pato iru awọn eeyan to waa ṣe akọlu naa ati idi ti wọn fi ṣe e ni gbogbo asiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.
Ọga ọlọpaa tesan Ikarẹ, SP Ọlatujoye Akinwande to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin ni awọn ti gbe ẹni to ku lọ si mọṣuari, nigba tawọn to fara gbọta ṣi wa nileewosan ti wọn ti n gba itọju.