Andrew Nice, awakọ BRT ti Bamiṣe wọ, loun o jẹbi ni kootu

Faith Adebọla, Eko

Ṣe ẹ ranti ọdọmọbinrin ẹni ọdun mejilelogun, Oloogbe Oluwabamiṣe Ayanwọla, to wọkọ BRT ijọba Eko lati agbegbe Lẹkki si Oṣodi, lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, to kọja, kawọn amookunṣika ẹda kan too da ẹmi rẹ legbodo, ti wọn si lọọ ju oku rẹ sori biriiji Carter, l’Erekuṣu Eko, lẹyin ọsẹ kan ti wọn ti n wa a. Awakọ BRT ọhun, Ọgbẹni Nice Andrew Omininikoron, ti loun o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an lori iku ọmọbinrin naa.

Afurasi ọdaran yii sọrọ yii nile-ẹjọ giga ipinlẹ Eko to wa ninu ọgba Tafawa Balewa Square, l’Erekuṣu Eko, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, nigba ti igbẹjọ tun bẹrẹ lakọtun lori ẹsun ti wọn fi kan an lori iku oloogbe naa.

Tẹ o ba gbagbe, wọn ti kọkọ fi oju afurasi ọdaran yii bale-ẹjọ Majisreeti kan to wa ni Yaba, lọsẹ to kọja, ṣugbọn adajọ naa loun fẹẹ gba imọran latọdọ ajọ to n fawọn adajọ nimọran, awọn agbofinro naa si beere aaye lati tubọ ṣiṣẹ iwadii siwaju si i, n ladajọ ba ni ki wọn ṣi taari Nice sọgba ẹwọn na.

Ninu alaye ti agbẹjọro awọn mọlẹbi naa ṣe f’ALAROYE lẹyin igbẹjọ, Ayọ Ademiluyi sọ pe wọn ti gbe ẹjọ naa kuro nile-ẹjọ Majisreeti, tori ẹsun apaayan ni, ile-ẹjọ giga nikan lo laṣẹ lati gbọ iru ẹjọ bẹẹ, idi niyẹn ti igbẹjọ fi bẹrẹ lakọtun.

“Ẹsun mẹrin kongba kongba ni wọn fi kan Nice Andrew, akọkọ ni pe o fipa ba Arabinrin Osezulu Nneka Maryjane laṣepọ. Awa o mọ ẹni arabinrin yii, ṣugbọn o ṣee ṣe ko jẹ ọkan lara awọn ti wọn tun fẹsun kan awakọ BRT pe o fipa ba awọn laṣẹpọ, wọn ni ninu ọkọ BRT naa lo ti huwa aidaa ọhun, lagbegbe LCC, ni Lẹkki, agbegbe naa yii kan naa ni oloogbe Bamiṣe ti wọ ọkọ BRT to n wa, to fi dẹni awati.

“Ẹsun keji ni pe o lẹdi apo pọ pẹlu awọn janduku mi-in lati ṣeku pa Bamiṣe Ayanwọla.

“Ẹsun kẹta ni pe o ba Bamiṣe laṣepọ lọna to lodi, eyi tawọn eleebo n pe ni sexual assault,

“Ẹsun kẹrin si ni pe oun lo pa Bamiṣe Ayanwọla.

Nigba ti Adajọ Ṣẹrifat Shonaike bi i leere boya o jẹbi tabi ko jẹbi, o loun o jẹbi,” Ademiluyi lo ṣalaye bẹẹ.

Ileeṣẹ to n gbeja awọn araalu sọ ni kootu pe awọn ṣi lawọn ẹsun mi-in tawọn fẹẹ fi kan afurasi ọdaran yii, ati pe ọpọ ẹri ati ẹsibiiti ti wa nikaawọ awọn lati le fidi awọn ẹsun naa mulẹ pe ododo ni.

Agbẹjọro olujẹjọ, Isaac Ikezwurem, beere pe ki kootu fun onibaara oun ni beeli, ṣugbọn adajọ ko gba, niṣe lo paṣẹ pe ki wọn da Nice pada sọgba ẹwọn ti wọn ti mu un wa.

Amofin Ademiluyi tun ṣalaye pe awọn mọlẹbi oloogbe naa ti kegbajare sijọba pe awọn o fara mọ ayẹwo iwadii tijọba fẹẹ ṣe si oku ọmọbinrin naa, wọn ni awọn fẹ kijọba gba wọn laaye lati gba akọṣẹmọṣẹ oluṣayẹwo ti yoo tuṣu desalẹ ikoko, lori iru iku ti wọn fi pa oloogbe naa.

Bakan naa lo lawọn mọlẹbi yii ko dunnu si iwa aibikita ti Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, hu si wọn lori iṣẹlẹ yii, o ni ihuwa ijọba Eko ko fihan pe wọn kaaanu awọn tiṣẹlẹ yii kan, ṣugbọn o ni awọn ṣi nigbẹkẹle ninu ile-ẹjọ lati ri idajọ ododo gba.

Ọkunrin naa gboṣuba fawọn ọlọpaa, o si bẹ wọn lati tẹpẹlẹ mọ wiwa awọn amookunṣika yooku, ki wọn si fimu wọn kata ofin.

Leave a Reply