Igbakeji Atiku tẹlẹ, Peter Obi, loun naa maa dupo aarẹ

Ọrẹoluwa Adedeji

Gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ, to tun jẹ ondupo igbakeji aarẹ pẹlu Alaaji Atiku Abubakar lọdun 2019, Peter Obi, ti fi erongba rẹ lati dupo aarẹ orileede yii ninu ẹgbẹ oselu PDP lọdun 2023 han.

Niluu Awka lo ti sọrọ naa lasiko to n ba awọn ọba alaye ati aarẹ awọn eeyan agbegbe mọkanlelọgọsan-an (181) sọrọ nile ijọba, nipinlẹ naa.

Ninu fidio kan to ṣe, eyi to gbe si ori ẹrọ abẹyẹfo (twitter), rẹ lo ti ṣalaye ọrọ naa niwaju awọn eeyan yii pe, ‘Ọmọ Naijiria ni gbogbo wa, a si mọ bi wọn ṣe n pin nnkan lorileede yii. Ọpọ eeyan lo ti n pe mi ti wọn n bi mi pe iha wo ni mo kọ si gbogbo ohun to n lọ yii, ohun ti mo si sọ fun wọn naa ni pe mo n fọrọ lọ awọn to ba yẹ lori rẹ lọwọ. Idi ti mo fi pe yin jọ sibi lonii ni lati sọ fun yin pe mo fẹẹ dupo aarẹ ilẹ Naijiria lọdun 2023.

‘‘Nigba ti mo wo orileede yii daadaa, mo ṣakiyesi pe ipinya ti wa laarin wa ju, ohun ti mo si ni lọkan ni lati ṣejọba le orileede to wa ni ọkan, to si ni eto aabo, lati le fa awọn ara ilẹ okeere wa, ki wọn waa da iṣẹ silẹ ni Naijiria.

‘‘Mo maa sọ Naijiria di orileede to n pese nnkan loriṣiiriṣii yatọ si orileede to gbọkan le ohun ti awọn orileede mi-in n ṣe. Bakan naa ni mo fẹ ki eto aabo to nipọn wa ni Naijiria. Ki i ṣe pe mo fẹẹ dupo oṣelu lasan, mo fẹẹ fi ara mi silẹ lati sin awọn eeyan orileede mi ni.

Naijiria ti emi maa dari yoo pese ise, yoo mu ọrọ aje ilẹ wa dagba, yoo si mojuto eto ẹkọ. Ti wọn ba fun mi ni anfaani, ma a ṣe atunṣe si orileede yii, ti iyatọ yoo si ba a.

‘‘Mo n fi asiko yii sọ fun yin pe mo maa dije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.’’

Ọdun 2006 si 2014 ni Obi fi ṣe gomina ipinlẹ Anambra labẹ ẹgbẹ oṣelu APGA, ọdun 2016 to kuro nipo naa lo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.  Ọdun 2019 lo si dije dupo igbakeji aarẹ ilẹ yii pẹlu Alaaji Atiku Abubakar toun naa dije dupo aarẹ.

Bi Obi ṣe bọ sita lati dije yii fopin si awuyewuye ati ariyanjiyan tawọn kan n sọ pe yoo jade, tawọn mi-in si n sọ pe ko ni i jade.

 

Leave a Reply