Ọlawale Ajao, Ibadan
“Bi ijọba ba ko ọlọpaa to ju ogun miliọnu lọ sigboro, wọn ko le ṣaṣeyọri lori eto aabo, niṣe niṣoro eto aabo to n koju orileede yii yoo tubọ maa tẹsiwaju, afi ti ijọba ba fi tawọn ọba ṣe.”
Aarẹ-Ọna-Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, lo sọrọ yii lasiko abẹwo to ṣe si Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Moshood Ọlalekan Iṣọla Balogun nile ẹ to wa laduugbo Alarere, nitosi Iwo Road, n’Ibadan, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2022 yii.
“Iba Adams, to tun jẹ olori ẹgbẹ OPC nilẹ yii, ṣalaye pe nigba ta a fi n ṣejọba ẹlẹkunjekun, a ni ohun ti a n pe ni igbimọ awọn lọbalọba. O yẹ ka gbe igbimọ yẹn dide pada kaakiri awọn ipinlẹ wa lasiko yii, nitori awọn ọba ni ipa pataki lati ko lori eto aabo.
“Nilẹ okeere, ninu ẹmi ni wọn ti kọkọ maa n fi agbara ibilẹ ṣẹgun ipenija eto aabo ko too di pe awọn ọlọpaa bẹrẹ si i lọọ koju awọn ọdaran. Ta o ba gba awọn ọba laaye lati maa ṣe iru eleyii, koda, bi ijọba ba ko ọlọpaa to ju ogun miliọnu lọ da saarin ilu, wọn o ni i ṣaṣeyọri, nitori wọn o fi tawọn alalẹ ṣe, ojuṣe awọn ọba si niyẹn.
Ile Aye ta a wa yii, awọn alalẹ lo n mojuto o, awọn ni wọn n mojuto ilẹ, omi ati imọlẹ, ṣugbọn taa ba ti pa awọn alalẹ ti, awọn naa yoo kawọ gbera, wọn yoo maa wo wa ni.”
Nigba to n bu ẹnu atẹ lu ọna ti awọn ara Ibadan gba dori aṣa kodo lasiko isinku Olubadan ana, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, Aarẹ-Ọna-Kakanfo sọ pe “ki Ọlọrun jẹ ki ọba yii pẹ lori itẹ. Ọba ki i ṣe ẹni ti wọn maa n sin bi wọn ṣe n sinku eeyan lasan. Ti ọba ba waja, wọn ni lati ṣe awọn eto ibilẹ kan, bii ki wọn pa ọja, bii ki wọn fi oro, ki awọn eeyan le mọ pe nnkan pataki ṣẹlẹ ninu ilu yẹn.
“Iru awọn nnkan bayii lo maa jẹ ki awọn eeyan bẹru awọn ọba. Wọn waa tori pe ọba ana jẹ Musulumi, wọn gbe oku ọba lọ si Mapo, gbogbo awọn eeyan wa n wo oku ọba, bẹẹ, ko yẹ ki awọn eeyan maa ri oku ọba.
Emi naa o fara mọ aṣa pe ki wọn maa yọ eya ara ọba o, mi o fara mọ aṣa ka maa feeyan rubọ rara, ohun ti mo n sọ ni pe ka maa ṣe awọn oro tawọn baba wa maa n ṣe nigba ti ọba ba waja, iyẹn lo maa n jẹ ki awọn ọba jọ awọn eeyan loju, to si maa jẹ ki ẹnu ọba ka awọn araalu to n jọba le lori.”
O waa rọ ijọba apapọ orileede yii lati wa ojuṣe pataki fawọn ọba ninu eto iṣejọba ilu.
Ninu ọrọ tiẹ, Ọba Balogun ti i ṣe Olubadan ilẹ Ibadan ṣeleri lati mu ayipada rere ba ilu nla naa lasiko ijọba toun.
Lara awọn to kọwọọrin pẹlu Iba Gani Adams
ni Ọnarebu Ọlaniyan Akọrọ ti i ṣe alakooso agba fẹgbẹ agbabọọlu 3SC, Ọnarebu Akeem Ige ati bẹẹ bẹẹ lọ.