Jọkẹ Amọri
Awọn eeyan to le diẹ ni mẹẹẹdọgbọn, ninu eyi ti alaboyun wa ninu wọn ni wọn fara pa lasiko idibo gbogbogboo ẹgbẹ APC to n lọ lọwọ ni Eagle Square, niluu Abuja.
Niṣe ni akọlukọgba waye, ti ọpọ awọn ti wọn wa nita si n wa ọna lati wọ inu gbọngan ti eto naa ti n lọ lọwọ. Lasiko naa ni wọn n rọ ara wọn gidigidi, nigba tawọn agbofinro si n gbiyanju lati le awọn eeyan naa ni wọn bẹrẹ si i ṣubu lu ara wọn. Eeyan to le ni mẹẹẹdọgbọn la gbo pe o ṣese, alaboyun kan si wa ninu wọn.
ALAROYE gbọ pe awọn aṣoju to fẹẹ dibo lasiko naa lo n mura lati wọle, bẹẹ ni awọn ti ọrọ ibo naa ko kan lọwọ kan lẹsẹ, ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa ya de lojiji, tawọn fẹẹ wọle. Niṣe ni wọn ti kinni bii fẹnsi ti wọn fi pako ṣe lati fi da awọn eeyan duro ki wọn ma baa raaye wọle wo, bi wọn si ṣe ti i wo bayii, niṣe ni onikaluku bẹrẹ si i wọle, ti wọn si n ti ara wọn.
O nira fun awọn ọlọpaa lati dari awọn ero naa pe ki wọn ma wọle, niṣe ni wọn si ju tajutaju lati le ọgọọrọ ero naa lọ. Bẹẹ ni wọn tun tu awọn aja wọn silẹ, eyi lọpọ awọn eeyan naa ri ti wọn fi ba ẹsẹ wọn sọrọ.
Baba agbalagba kan wa ninu awọn to ṣubu lulẹ naa, bẹẹ ni alaboyun kan naa ṣubu, ti awọn to wa nibẹ si gbiyanju lati gbe e dide.
Awọn ọlọpa atawọn agbofinro yooku lọọ ko ara wọn wa lọpọ si i ni wọn too ri alaafia pe pada si ayika naa.