Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun marundinlogoji kan, Agbebaku David, lori ẹsun pe o n pe ara rẹ ni ohun ti ko jẹ lati fi lu jibiti kaakiri.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Ọlawale Ọlọkọde, salaye nigba to n ṣafihan David atawọn meji mi-in ti ọwọ jọ ba, ni ọdun 2015 ni David sa kuro nidii iṣẹ ṣọja, latigba naa lo si ti bẹrẹ si i lu awọn araalu ni jibiti.
O ni lẹyin to sa kuro lẹnu iṣẹ naa lọdun 2015, ọdun 2020 ni wọn too ri i mu, ti awọn alaṣẹ si le e kuro lẹnu iṣẹ lẹyin ti wọn gba gbogbo nnkan wọn lọwọ ẹ.
Lẹyin eyi lo tun gba ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira lọwọ ẹnikan, to si sa lọ. Nigba ti ẹni naa ko gburoo rẹ mọ lo lọọ fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti, ti wọn si bẹrẹ si i wa a, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ lọjọ keji, oṣu Kẹta, ọdun yii.
Iwadii fi han gẹgẹ bi Ọlọkọde ṣe sọ pe David ti figba kan ṣẹwọn niluu Akurẹ lori ẹsun pipe ara ẹni ni ohun ti a ko jẹ ati ole jija, ọgba ẹwọn Olokuta, nipinlẹ Ondo, lo si wa laarin ọdun 2019 si 2020, ki wọn too tu u silẹ, sibẹ ko jawọ ninu iwa to n hu.
Nigba ti wọn mu un ninu oṣu Kẹta, ọdun yii, o jẹwọ pe ọmọkunrin kan, Ajibọla Ibrahim, lawọn jọ n ṣiṣẹ, ati pe o ti figba kan ba oun ta ọkọ Honda Accord to ni nọmba RGB-399-MB fun ẹnikan niluu Abẹokuta.
Ọlọkọde sọ siwaju pe lasiko ti David ati Ibrahim lọ si ileeṣẹ ti wọn ti n gba lansẹnsi lati gba nọmba si ọkọ kan pẹlu aṣọ ṣọja ti wọn wọ ni ọwọ tẹ wọn. O ni ni kete ti iwadii ba ti pari ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.
Lara awọn nnkan ti wọn ba lọwọ David ni kaadi idanimọ ṣọja mẹrin, iwe-ẹri ileeṣẹ ologun kan, aṣọ ati fila ṣọja oriṣiiriṣii, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ati bẹẹ bẹẹ lọ.