Emi ni ẹgbẹ APC maa fa kalẹ lati dupo aarẹ lọdun 2023-Yahaya Bello

Jọkẹ Amọri

Bo tilẹ jẹ pe agbegbe kan naa ni Abdullahi Adamu ti wọn ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bii alaga gbogbogboo ẹgbẹ oṣelu APC ati Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, ti wa, eyi to si le ma fun ẹni to ba fẹẹ dije dupo aarẹ ni anfaani lati tun wa lati ibẹ, sibẹ, gomina yii ni oun nigbagbọ ati idaniloju pe oun ni tikẹẹti lati dupo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo ọdun to n bọ maa ja mọ lọwọ.

Nigba to n sọrọ lori eto kan ti wọn pe ni Sunrise Daily, ti ileeṣẹ Tẹlifiṣan Channels gbe kalẹ lo ti sọ pe to ba jẹ pe ilana fifa ọmọ oye kalẹ, (concensus) ni wọn lo, tabi idibo abẹle lo waye, bo si jẹ gbangba-laṣa-a-ta, iyẹn direct primary naa ni, oun naa loun maa pada gba tikẹẹti lati dije lorukọ ẹgbẹ APC.

Bello ni ibi ti alaga awọn ti wa tabi pe wọn pin ipo naa si agbegbe kan ko ni nnkan kan an ṣe pẹlu erongba oun lati di aarẹ. O ni oun maa dupo aarẹ naa nibi ibo abẹle ẹgbẹ awọn, oun ni wọn si maa pada fun ni tikẹẹti naa lai fi ti agbegbe ti oun ti wa ṣe.

O fi kun un pe ẹgbẹ naa nilo ẹni ti ko ti i dagba, to ni oye, to si gbọn ṣaṣa, lati dupo aarẹ. O ni oun si ni idaniloju pe ẹgbẹ oun yoo fa oun kalẹ lati dije lorukọ wọn.

Bello ni nigba ti oun ba gba tikẹẹti naa tan, gbogbo ọrọ pe agbegbe kan ni ẹnikan yoo ti wa yoo yanju ara rẹ gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ nibi ipade ti awọn ti yan alaga ẹgbẹ niluu Abuja ni Satide to kọja yii, nitori ọna to daa ju ni ẹgbẹ naa yoo lo lati yan ọmọ oye ti yoo dije.

Leave a Reply