Gbemiga Amọs, Abẹokuta
Ija ajaku akata to n lọ laarin awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun nipinlẹ Ogun ko ti i rọlẹ rara, eeyan mẹjọ la gbọ wọn tun ṣeku pa laarin ara wọn niluu Ṣagamu, loru ọjọ Aiku, Sannde, mọju Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta yii.
Ba a ṣe gbọ, wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Aiye’ ati ‘Ẹiyẹ’ ni wọn n gbẹsan lara ara wọn, niṣe ni wọn n wa ara wọn kirakita kaakiri ilu naa, ti wọn si n ṣa ara wọn balẹ.
Awọn ọmọ alaigbọran naa paayan si adugbo Soyinbo, Ijagba, Sabo ati Ajegunlẹ. Wọn pa oniṣe ọwọ kan torukọ ẹ n jẹ Akeem ni nnkan bii aago meje owurọ ọjọ Aje, wọn ni aake ati ada ni wọn fi ṣa a yannayanna to fi ku.
A gbọ p’awọn ọlọja ko le patẹ ọja wọn lawọn agbegbe tija naa ti waye, niṣe ni wọn tilẹkun mọri.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, bo tilẹ jẹ pe eeyan meji pere lo loun ṣi gbọ pe wọn pa, ṣugbọn o lawọn ti mu lara awọn ọmọ onija naa sahaamọ, awọn agbofinro si ti n ba iṣẹ ipese aabo lọ nibẹ.
Tẹ o ba gbagbe, lọsẹ to lọ yii lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ṣoro funra wọn ni agbegbe Adigbẹ si Oluwo, niluu Abeokuta, wọn pa ẹni kan, wọn ṣe ọpọ leṣe, awọn ọlọpaa si mu afurasi mejidinlogun ninu wọn.