Ọwọ tẹ manija otẹẹli to fẹẹ fi tipatipa ṣe ‘kinni’ fun agunbanirọ l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Manija ileetura kan niluu Oṣogbo, Joseph Adelẹyẹ, ti n ka boroboro lagọọ ọlọpaa bayii lori idi to fi fẹẹ fi tipatipa ba agunbanirọ kan lajọṣepọ ninu otẹẹli wọn.

Agunbanirọ naa lo n sinru ilu nipinlẹ Ọṣun, otẹẹli kan to wa ninu GRA, niluu Oṣogbo, lo si ti n ṣiṣẹ (PPA).

Ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, la gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ laago mẹsan-an alẹ ku ogun iṣẹju ninu ọkan ninu awọn yara to wa nibẹ.
Agunbanirọ naa, ẹni ti a forukọ bo laṣiiri, sọ pe ṣe ni Joseph sọ pe ki oun mu ọti bia kan wa, o si sọ pe ki oun tẹle oun (Joseph) lọ sinu yara kan.
Lẹyin to gba ọti bia lọwọ rẹ tan lo bẹrẹ si i ba a sọrọ nipa ohun to fẹẹ ṣe lẹyin to ba pari isinru ilu. O ni ko pẹ rara to fi bẹrẹ si i fi ọwọ tẹ oun lara.
O ni, “Nigba ti mo ri i pe o ti n fọwọ pa mi lara ju, mo gba ọwọ rẹ kuro lara mi, ṣugbọn lojiji lo fa mi mọra, o fi ẹyin mi le bẹẹdi, o ki ọwọ bọ inu ṣokoto mi, o si ki ọwọ bọ mi loju-ara.
“O fa ṣọkoto mi walẹ, o n gbiyanju lati ki ‘kinni’ rẹ bọ mi loju-ara, ni gbogbo asiko yii ni mo n wọya ijakadi pẹlu rẹ, bo tilẹ jẹ pe o ṣe firigbọn ju mi lọ, mo pariwo, ṣugbọn ko sẹni to gbọ, ẹẹkan naa ni mo ge e leyin jẹ, lo ba da omira (semen) si ara mi ati si pata ti mo wọ, sibẹ, n ko dawọ ijakadi yii duro, nigba to ri i pe n ko le mi daadaa mọ lo fi mi silẹ, o si sa lọ.

“Lọjọ keji, meji lara awọn ti a jọ n ṣe agunbanirọ kiyesi i pe n ko ṣe daadaa bi mo ṣe maa n ṣe tẹle, wọn beere pe ki lo ṣẹlẹ, n ko kọkọ fẹẹ sọ fun wọn tẹlẹ, ṣugbọn nigba ti mo bẹrẹ si i sunkun, wọn ba mi sọrọ, mo si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wọn, a si fẹnuko pe ki n fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti.
“Lagọọ ọlọpaa Dugbẹ, awọn ọlọpaa tẹle mi lọ si otẹẹli yẹn, ṣugbọn bi manija ṣe gburoo wa lo gba ẹyinkule sa lọ. Lẹyin ọjọ kẹta ni wọn too ri i mu.”
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe ọmọkunrin naa ti wa lakolo ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran, iwadii si ti bẹrẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Leave a Reply