Nitori ẹsun ijinigbe, ile-ẹjọ sọ Fulani darandaran mẹfa sẹwọn gbere ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ni ile-ẹjọ giga kan to fi ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ṣe ibujokoo sọ awọn Fulani darandaran mẹfa kan, Tambaya Abubakar, Babuga Umaru, Shehu Umaru, Mojumba Bello, Abubakar Juli ati Mamma Lawali sẹwọn gbere fẹsun ijinigbe ati iwa ọdaran miiran to fara pẹ ẹ.
Onidaajọ Hannah Ajayi, lo paṣẹ pe ki awọn ọdaran mẹfa ọhun lọọ lo gbogbo eyi to ku nile aye wọn lọgba ẹwọn latari pe wọn jẹbi ẹsun igbimọ pọ, ijinigbe, ati gbigbe ohun ija oloro kiri lọna aitọ. Olupẹjọ gbe awọn ọdaran Fulani ọhun lọ siwaju ile-ẹjọ pe ni ọdun 2017 ni wọn gbimọ-pọ ji Usman Mohammed gbe pẹlu ibọn niluu Osi, nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara. Nigba ti wọn si gbe e lọ sinu igbo, wọn n beere ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (N400,000), gẹgẹ bii owo itusilẹ lọwọ awọn mọlẹbi rẹ ko too di pe ọwọ tẹ wọn. Dajọ Hannah Ajayi paṣẹ pe ki awọn ọdaran naa maa lọ sẹwọn gbere, ki wọn lọọ lo iyooku aye wọn.

Leave a Reply