Gbenga Amos, Abeokuta
Kayeefi lọrọ ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọnkan, Sikiru Ibrahim. Baba to bi i lọmọ lo binu yọ ada si bii alapata to fẹẹ ṣa maaluu, bẹẹ lo ṣe ṣa baba ẹ pa, tori iyẹn bi i lere idi to fi n sun lasiko to yẹ ko wa’ṣẹ aje ṣe.
Ba a ṣe gbọ, iṣẹ ọlọdẹ ni Oloogbe Mumuni Ibrahim n ṣe, oun si ni Baba Sikiru, ibi iṣẹ ọdẹ to ṣe mọju ni wọn lọkunrin naa ti n bọ laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ oṣu Kẹta to kọja yii.
Bi baba naa ṣe wọle rẹ to wa laduugbo Onipaanu ti wọn n gbe, o ya a lẹnu pe ọmọ rẹ, Sikiru, ṣi wa lori bẹẹdi to sun bii ọlẹ. Eyi lo mu ki baba naa beere pe iru oorun wo lọmọ oun n sun lataarọ tilẹ ti mọ, toloko ti gbọna oko, tolodo si ti wa lọna odo, ti gbogbo aye ti wa nibi ti wọn ti n mu iṣẹ aje ṣe.
Wọn ni kaka ti Sikiru iba fi yira pada lati gbọrọ si baba rẹ lẹnu, niṣe lo sọrọ dija, bo si ṣe dide lori ibusun rẹ, ada lo fa yọ lojiji, lo ba sọ baba rẹ di ẹran maaluu, lo ṣa a yannayanna.
Iboosi oro ti baba naa ke lo ta awọn aladuugbo lolobo, Ọgbẹni Abiọdun Sunday to debi iṣẹlẹ ọhun lo sare gba teṣan ọlọpaa to wa ni Onipaanu lọ lati fi ohun to ṣẹlẹ to wọn leti.
Kia ni DPO teṣan naa, CSP Job Bamidele, ti yanṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ pe ki wọn lọọ wadii ohun to ṣẹlẹ, nigba ti wọn debẹ, wọn ba Sikiru, wọn si ba baba naa to n japoro iku, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe jagunlabi, wọn si gbe baba ẹ digbadigba lọ sileewosan jẹnẹra fun itọju pajawiri.
Nigba tilẹ ọjọ keji yoo fi mọ, ẹpa o boro mọ fun Mumuni, o dagbere faye lọsibitu naa, awọn ọlọpaa si ti yọnda oku rẹ fawọn mọlẹbi ẹ lati le sin in nilana ẹsin Musulumi to n ṣe.
Wọn beere lọwọ Sikiru pe ki lo fa a to fi sọ baba to bii lọmọ di suya, wọn lọrọ radarada kan lo n sọ lẹnu, ko ri alaye to gunmọ kan ṣe, ko si sọ boya baba naa ti ṣẹ oun tẹlẹ ni.
Ṣugbọn wọn fura pe afaimọ ki ọmọkunrin naa ma ti darapọ mọ ẹgbẹ okunkun kan, wọn ni iṣe ati iwa pẹlu ọrọ rẹ jọ tẹlẹgbẹ imulẹ gidi.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti paṣẹ pe ki afurasi apaayan yii ṣi wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n ṣiṣẹ iwadii lori ẹsun rẹ, iwadii naa lo maa sọ igbesẹ to kan lori iwa ọdaran to hu yii gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe sọ ninu atẹjade rẹ.