Faith Adebọla
Pasitọ agba ijọ Salvation Ministry, David ibiyeomie, ti gba awọn obi niyanju lati ma ṣe ra foonu fawọn ọmọ wọn ti ko ba ti i wọ ile ẹkọ giga.
Ojiṣẹ Ọlọrun yii fi ọrọ naa lede lori ẹrọ ayelujara Fesibuuku(facebook) rẹ, o ni, “Ẹ ma ṣẹ ra foonu f’ọmọ ti ko ba ti i wọ yunifasiti. O le ri bakan bakan leti, mo si mọ pe ẹ laju, ṣugbọn ẹ ma ṣe bẹẹ.
Ẹ ma ra foonu fun wọn, iyẹn ki i ṣe iwa ọlaju, awọn foonu nla tẹ ẹ n ri yẹn, oriṣiiriṣii awọn nnkan ko-tọ lo maa n deede sa wa soke, ti ko si yẹ fawọn ọmọde lati ri, awọn foonu tiyin wa nibẹ fun wọn lati lo, ẹ jẹ ki wọn maa lo foonu tiyin na, ẹ si le ra tẹlifoonu ori tabili kẹ ẹ gbe e sinu palọ yin fun lilo awọn ọmọ ati gbogbo ẹbi”.
Ikilọ ojiṣẹ Ọlọrun yii o ṣẹyin fidio kan to n ja ranyin lori afẹfẹ, nibi ti awọn akẹkọọ ileewe Chrisland to wa ni agbegbe Lekki, niluu Eko, ti gbe fidio ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹwaa kan to jẹ akẹkọọ ileewe ọhun lakooko to n ni ajọṣepọ pẹlu awọn akẹkọọ ọkunrin nigba ti wọn lọ si Dubai.
Ọrọ yii di ohun ti awọn ọmọ Naijiria n fa mọra wọn lọwọ lori afẹfẹ, nibi ti awọn kan ti n sọ pe ki wọn fi panpẹ ofin de ileewe ọhun, awọn mi-in ni ọwọ awọn obi ọmọ ni ọrọ naa ti wọ wa, awọn si lo yẹ ki wọn da lẹbi iwa adojutini ti ọmọ wọn hu nitori ki i ṣe ileewe lo kọ ọ ni iwa aitọ ọhun.
Bakan naa, awọn miiran ni ko yẹ ko jẹ pe ariwo ọmobinrin yẹn nikan ni wọn yoo maa pa, ki i kuku ṣe pe o da kinni ọhun ṣe funra rẹ, awọn ọkunrin ti wọn jọ ṣe e nkọ?
Ta o ba gbagbe, ni kete ti ọrọ yii ṣẹlẹ ni ijọba ipinlẹ Eko ti gbe agadagodo nla sẹnu ọna ileewe ọhun, wọn si ṣe ikilọ pe ki wọn ma ṣe gbe fidio ọhun sori afẹfẹ mọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti bẹrẹ iwadii ni pẹrẹu lori iṣẹlẹ yii. Wọn ni awọn o ri i daju pe awọn tuṣu desalẹ ikoko lati wa ojutuu sọrọ naa.