Eeyan meji ku lasiko ti awọn Hausa ati tọọgi kọju ija sira wọn niluu Ẹdẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
O kere tan, eeyan meji lo ti rọrun aremabọ, nigba ti ọpọlọpọ fara pa yanna-yanna lasiko ti awọn tọọgi kan atawọn eeyan agbegbe Sabo, niluu Ẹdẹ, nipinlẹ Ọṣun, kọju ija sira wọn.
Gẹgẹ bi Alaroye ṣe gbọ, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wahala naa bẹrẹ nigba ti awọn Hausa naa pajuda si awọn tọọgi ti wọn ti n fi ọpọ ọjọ sẹyin gba owo lọwọ wọn.
A gbọ pe ọkunrin kan ti inagijẹ rẹ n jẹ ‘ọlọpaa’, ẹni to jẹ igbakeji ogbologboo awọn tọọgi kan ti awọn ọlọpaa ti n wa, Hammed Rasidi (Ọkọ-Ilu), lo ṣaaju awọn tọọgi ọhun.
Ṣaaju la gbọ pe Seriki Hausa, Ibrahim Gambo, ti kọkọ fi ẹjọ ‘Ọlọpaa’ sun Ọkọọlu lori bo ṣe n fi ojoojumọ yọ awọn eeyan Sabo lẹnu, Ọkọọlu si pe ọkunrin naa lati kilọ fun un, ṣugbọn ko gbọ, idi niyi ti Ọkọọlu fi sọ fun Seriki pe eyikeyii ti ọwọ ba ti tẹ ninu wọn, ki wọn ma ṣe fi le awọn ọlọpaa lọwọ o, ṣe ni ki wọn ṣe e bi ọṣẹ ṣe n ṣe oju.
Ninu ọrọ rẹ, Seriki Hausa niluu Ẹdẹ, Gambo, ṣalaye pe gbogbo igba lawọn tọọgi naa n yọ agbegbe Sabo, ninu eyi ti Hausa, Fulani, Yoruba atawọn ẹya miiran wa, lẹnu.
O ni, “Ko si Ọkọ-Ilu ninu awọn to n da wahala yii silẹ, loootọ awọn ọmọlẹyin rẹ lawọn tọọgi yẹn, ọkunrin kan toun naa fẹẹ gba ipo adari awọn tọọgi lọwọ Ọkọọlu nitori pe ko si nile lo da wahala naa silẹ.

“Lasiko wahala yẹn, eeyan marun-un ni wọn fara pa. A ko ti i le sọ ni pato boya ẹnikẹni ku. Marun-un lawọn tọọgi ti wọn wa si Sabo, wọn si n yinbọn lakọlakọ, ẹni to ko wọn wa, Ọlọpaa, ti ku bayii.
“A ko mọ bo ṣe ku, nitori awọn agbofinro naa wa nibẹ, ibọn n dun kaakiri ni. A dupẹ lọwọ Gomina Oyetọla ati Kọmiṣanna ọlọpaa, Ọlọkọde, fun ipa wọn lati da alaafia pada siluu Ẹdẹ”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn tọọgi kan lọ si agbegbe Sabo, niluu Ẹdẹ, wọn si gba awọn ọkada to jẹ ti awọn Hausa, amọ ṣa, awọn eeyan agbegbe naa doju ija kọ wọn, eeyan kan si gbẹmi-in mi.

Leave a Reply