Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi pampẹ ofin gbe awọn ikọ adigunjale ẹlẹni mẹta kan ti wọn n yọ awọn eeyan ilu Ọwọ ati agbegbe rẹ lẹnu lati bii oṣu diẹ sẹyin.
Ni ibamu pẹlu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, fi ṣọwọ si wa, orukọ awọn afurasi adigunjale tọwọ tẹ ọhun ni: Vincent Pascal, ẹni ọdun mọkanlelogun, John Samuel ati Tersoo Godwin, ti wọn jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun.
Pascal atawọn ẹgbẹ rẹ lo ni ọwọ tẹ ni abule kan ti wọn n pe ni Ashawo, nitosi Amurin, nijọba ibilẹ Ọwọ, laarin ọsẹ to kọja.
Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun ta a wa yii, lo ni awọn mẹtẹẹta lọọ digun ja awọn eeyan kan lole labule David, eyi to wa loju ọna marosẹ Ọwọ si Ikarẹ Akoko, ti wọn si gba owo to to bii ẹgbẹrun lọna igba le mẹta Naira (#203,000) lọwọ wọn.
Lara awọn nnkan to ni awọn ka mọ awọn afurasi ọdaran ọhun lọwọ ni aake meji, iboju mẹrin, ọpọlọpọ igbo atawọn ohun ẹṣọ ara.
Ọdunlami ni awọn tọwọ tẹ naa ko ni i pẹẹ foju bale-ẹjọ niwọn igba ti wọn ti fẹnu ara wọn jẹwọ ipa ti wọn ko ninu iwa ọdaran to n waye lagbegbe Ọwọ naa.