Ibrahim Alagunmu
O kere tan, eeyan mẹta lo ti rọrun alakeji, nigba ti ọpọlọpọ fara pa yanna-yanna lasiko ti awọn tọọgi kan kọju ija sira wọn, eyi to pada di tawọn ọmọ ogun orilẹ niluu Ọffa, nipinlẹ Kwara.
Gẹgẹ bi ALAROYE ṣe gbọ, ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni wahala naa bẹrẹ laarin awọn oriṣii tọọgi meji ọtọọ, ti wọn doju ija kọra wọn ni Opopona Aafin ọba Ọffa, ti wọn bẹrẹ si i fi ada ati kumọ le ara wọn kiri. Ni kete tawọn ọmọ ogun ori ilẹ (NAVY) gbọ ni wọn fẹ lọọ pẹtu si wọn laarin, ṣugbọn bi wọn ṣe gunlẹ sibẹ ni nnkan tun bọ buru si i.
A gbọ pe, ni nnkan bii aago mẹjila ọsan ni wahala naa bẹrẹ, bi awọn ọmọ ogun ṣe de si agbegbe naa ni awọn tọọgi yii yari kanlẹ, ti wọn si bẹrẹ si i doju ija kọ awọn ọmọ ogun, ni wọn ba jọ n yinbọn sira wọn, ọpọ dukia ṣofo, ẹmi mẹta bọ, ọpọ si fara pa.