Henry ji ọkọ ajagbe l’Ekoo, Ọrẹ lọwọ ti tẹ ẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkunrin ẹni ọdun mejidinlaaadọta kan, Henry Okoduwa, lọwọ ti tẹ ẹ pẹlu ọkọ ajagbe kan to ji gbe niluu Eko, to si fẹẹ lọọ lu u ta ni gbanjo ni Onitsha, nipinlẹ Anambra.
Henry ni wọn lo bọ sọwọ awọn ọlọpaa laarin oju ọna marosẹ Ọrẹ si Benin, lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ni awọn ti kọkọ gba ipe pajawiri kan ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ ọjọ naa pe ọkọ ajagbe alawọ funfun Iveco kan ti nọmba rẹ jẹ T6917LA, eyi ti wọn ji gbe lati ipinlẹ Eko fẹẹ gba ọna marosẹ Ọrẹ si Benin kọja.

O ni bi ọkọ naa ṣe n de ọdọ awọn agbofinro ni wọn da a duro, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe Henry, iyẹn awakọ to ji ọkọ ọlọkọ gbe.
O ni ọkunrin agbewiri naa yoo foju bale-ẹjọ laipẹ, nitori o ti fẹnu ara rẹ jẹwọ lasiko tawọn n fọrọ wa a lẹnu wo pe loootọ loun huwa buruku naa.
Ọdunlami ni ṣaaju lọwọ awọn ti kọkọ tẹ awọn baba agbalagba meji kan ninu ilé-ìtura ti wọn fi ṣe ibuba l’Akurẹ.
Awọn mejeeji, Abdulrasheed Adeyẹmi, ẹni ọdun mọkanlelaaadọta, ati Oluwaṣina Akeem to jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgọta ni wọn wa lati ipinlẹ Kwara pẹlu erongba ati waa tẹwọ gba ọkọ Toyota Hilux kan ti wọn ji gbe.
O ni ninu ifọrọwanilẹnuwo tiawọn ṣe fun awọn afurasi naa lo ni wọn ti jẹwọ pe ẹnikan ti wọn porukọ rẹ ni Johnson, ẹni ti wọn jọ pade lọgba ẹwọn lo tan awọn wọ inu iṣẹ ole jija.
Bakan naa lo ni wọn tun sọ fawọn ọlọpaa pe Alaaji kan ti wọn n pe ni Aliu Isah, ẹni to fi ipinlẹ Sokoto ṣe ibugbe ni onigbọwọ awọn.
Gbogbo awọn tọwọ tẹ naa lo ni wọn yoo foju ba ile-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply