Monisọla Saka
Awọn gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun ati Ọṣun, Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba ati Bisi Akande, ti pe ipade awọn oludije dupo aarẹ lapa Guusu Iwọ Oorun Naijiria ṣaaju ibo abẹle APC to n bọ lọna.
Gẹgẹ bi iwe iroyin PUNCH ṣe sọ, koko pataki ti ipade ọhun fẹẹ da le lori ni fun apa Guusu Iwọ Oorun lati fori kori lati yan ẹni kan lasiko ibo abẹle gẹgẹ bi ọpọ eeyan ṣe fifẹ han lati apa ibẹ fun ipo aarẹ.
Ipade ọhun ti wọn ni yoo waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹfa, oṣu karun-un, ọdun yii.
ALAROYE gbọ pe wọn fẹẹ ṣepade ọhun ki awọn eekan ninu ẹgbẹ APC le din iye awọn to fẹẹ dupo aarẹ ọdun 2023 ku, ki apa Iwọ Oorun le lanfaani lati ni tikẹẹti ipo aarẹ labẹ APC.
Lara awọn ti wọn n reti nibi ipade ti yoo waye ni Lagos House, Marina, l’Ekoo ni, Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu, Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Oṣinbajo, Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi ati Sẹnetọ Ibikunle Amosun.
Bakan naa ni wọn n reti Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin, Fẹmi Gbajabiamila, Ọjọgbọn Ajayi Boroffice, awọn gomina apa Iwọ Oorun lẹgbẹ APC pata, atawọn leekan leekan mi-in.
Awọn to ti ferongba wọn han lẹgbẹ oṣelu APC lapa Iwọ Oorun Naijiria lati dupo Aarẹ ni, Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, (Ogun), Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin tẹlẹri, Dimeji Bankọle(Ogun), Sẹnetọ Ibikunle Amosun (Ogun), Aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu (ipinlẹ Eko), Alaga awọn gomina nilẹ Naijiria, Dokita Kayọde Fayẹmi (ipinlẹ Ekiti).