Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ẹgbẹ PDP ipinlẹ Ekiti ti juwe kikede ti Gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde Fayẹmi, kede niluu Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, pe oun fẹẹ dije fun ipo aarẹ orile-ede yii niluu Abuja gẹgẹ bii ikede ofo ti mu ọgbọn kankan lọwọ.
Ẹgbẹ alatako naa sọ pe Fayẹmi fi ọpọlọpọ miliọnu owo ipinlẹ Ekiti kede ero rẹ pe oun fẹẹ dije dupo aarẹ, lẹyin to ti fowo awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ati ajẹmọnu owo-oṣu wọn silẹ lai san, ti ebi si n pa awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ekiti.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin ẹgbẹ PDP l’Ekiti, Ọgbẹni Raphael Adeyanju, fọwọ si l’Ọjọruu, Wesidee, lo ti sọ pe o jẹ ibanujẹ fun gbogbo ọmọ ipinlẹ Ekiti pe gbogbo awọn to wa nibi ti gomina naa ti kede ero rẹ naa ni wọn lọ lati ipinlẹ Ekiti siluu Abuja, eyi to jẹ pe ijọba ipinlẹ Ekiti lo san owo ọkọ wọn de ọhun.
O fi kun un pe iwadii ati ẹri to wa lọwọ awọn fihan pe bii ọọdunrun miliọnu (N300 miliọnu) ni gomina naa na lati kede ero rẹ yii, nigba to na bii biliọnu kan lati ṣe abẹwo kaakiri gbogbo ibi to lọ.
Adeyanju pe gomina ipinlẹ Ekiti yii nija pe ko sọ pato awọn ohun idagbasoke to ti dawọ le lati ọdun mẹta aabọ to ti gba eeku ida iṣejọba ipinlẹ naa, ti yoo mu un kunju oṣuwọn lati jẹ aarẹ orilẹ-ede Naijiria.
“Gbogbo olugbe ipinlẹ Ekiti ni ko le sun pẹlu ifọkanbalẹ, gbogbo ọna to wa nipinlẹ naa lawọn ajinigbe ti gba silẹ pẹlu bi wọn ṣe n ji awọn eeyan gbe, ti wọn si n gba owo gọbọi lọwọ wọn.