Monisọla Saka
Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Yẹmi Oṣinbajo, sọ pe ọdun pataki ti wọn maa n ṣe ni ilu Kano, iyẹn Durbar, ki i ṣe iran wiwo lasan, bi ko ṣe pe o tun n gbe ẹwa ati aṣa ilẹ wa ga.
Agbenusọ Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo, Laolu Akande, lo sọ eyi di mimo ninu atẹjade kan niluu Abuja. O sọ pe Igbakeji Aarẹ wa nibi ayẹyẹ ọdun Durbar ọba Kano ti awọn Kano Emirate Council ṣagbekalẹ rẹ lati ṣami ọdun itunu awẹ ọdun 2023 niluu ọhun.
Ọṣinbajo to jẹ alejo pataki nibi ayẹyẹ ọhun ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ọdun Durbar, lẹyin naa ni wọn ṣe abẹwo pataki si Emir ilu Kano, Ado Bayero.
Ọkunrin naa gboriyin nla fun awọn ti wọn ṣagbekalẹ eto ọhun atawọn to kopa ninu ayẹyẹ ọdun pataki Durbar ọhun ti wọn tun n pe ni ‘Hawan Daushe’ lede Hausa.
Ọjọgbọn Oṣinbajo ṣapejuwe ọdun Durbar bii iran arimaleelọ, ohun gbogbo n tan yinrinyinrin, gbogbo awọn nnkan teeyan yoo fi mọ pe Kano gan-an loun wa.
Nigba to de ẹnu ọna aafin Emir ilu Kano, Oṣinbajo gbadura ilọsiwaju ati igbega fun ilu naa atawọn eeyan to n gbe nibẹ. O dupẹ lọwọ Emir fun alejo nla ati itọju rẹ si i. O ni, “Eyi ni lati tọrọ ire ati ohun daadaa fun iwọ Emir atawọn eeyan ilu, mo si gbadura pe akoko ati ijọba rẹ yoo tubọ maa toro, yoo si maa mu itẹsiwaju ohun rere wa. Mo tun dupẹ lọwọ gomina, mo si gbadura fun alaafia ati aabo to peye ni ipinlẹ yii”.
Bayero gbadura pe ki Ọlọrun fun un ni aṣeyọri ninu irinajo ati erongba ọjọ iwaju rẹ naa.
Ọba alaye ọhun tun dupẹ lọwọ Oṣinbajo fun jijẹ to jẹ ipe rẹ, to si fi ijokoo pọn wọn le, o jẹ ko di mimọ pe ijokoo rẹ mu iyi nla ba aṣeyẹ ọhun.
Ninu ọrọ Emir, o ni, “Mo mọ ohun ribiribi ti Igbakeji Aarẹ ti ṣe lati mu idagbasoke ba orilẹ-ede wa nigba gbogbo, koda bo ṣe tun jẹ pe oun naa tun ni kọmiṣanna fun eto idajọ nigba kan”. Mo gba a ladura pe gbogbo ohun ire to ba n wu ọ lọkan lọjọ iwaju, Allah yoo fun ọ ṣe ni aṣeyọri.
‘‘Wiwa ti Igbakeji Aarẹ wa yii yoo tubọ buyi kun ọdun Durbar, nilẹ yii nikan kọ o, amọ nilẹ adulawọ ati agbanla aye” .
Emir tun tẹsiwaju, o ni,”A tun n foju sọna lati tun gba Igbakeji Aarẹ lalejo fun ọdun Durbar ilu Kano lọjọ iwaju, a si n gba a lero lati pese ẹṣin kalẹ fun un, koun naa le gun un, ko si tun kopa ninu ere ije Durbar “. Emir tun fi anfaani ọhun ki Aarẹ ilẹ yii, Muhammadu Buhari, o gbadura fun alaafia, eto aabo to gbopọn ati iduro deede fun orilẹ-ede Naijiria ati kaakiri agbaye.
Bakan naa, Gomina Abdullahi Ganduje ti ipinlẹ Kano dupẹ lọwọ Igbakeji Aarẹ fun wiwa si ipinlẹ wọn lati waa ba wọn dawọọ idunnu ọdun Durbar ati aafin wọn to ṣabẹwo si. O ni awọn nnkan wọnyi ṣe pataki fun imuduro aṣa, iṣẹmbaye, ibagbepọ to mu alaafia wa laarin awọn oniruuru ẹya to wa ni Kano, ati imugbooro eto ọrọ aje ni ipinlẹ naa.
Lara awọn ti wọn ba Ọṣinbajo kọwọọrin lọ sibi ọdun Durbar ilu Kano ni: Sẹnetọ Kabiru Gaya, ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin, Hafiz Kawu, Oludamọran pataki lori awọn nnkan amuluudun, Ahmad Zakari, Alwan Hassan atawọn mi-in.