Ọlawale Ajao, Ibadan
Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ọyọ lorukọ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), Sẹnetọ Kọla Balogun, ẹni to fibinu kuro ninu ẹgbẹ oṣelu ọhun, ti dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ, APC.
Ṣugbọn ọpọ ninu awọn alatilẹyin ọkunrin oloṣelu naa to jẹ aburo Ọba Lekan Balogun ti i ṣe Olubadan ilẹ Ibadan, sọ pe inu ẹgbẹ PDP lawọn ṣi wa, awọn ko ba a lọ sinu ẹgbẹ tuntun to lọ.
Ọkan ninu awọn alatilẹyin Balogun, ẹni ti ko fẹ kawọn oniroyin darukọ oun, ṣalaye pe latigba ti sẹnetọ yii ti fi ẹgbẹ PDP silẹ loun ati pupọ ninu awọn ti awọn jẹ atilẹyin rẹ ti pada lẹyin rẹ nitori awọn ko ṣetan lati kuro ninu ẹgbẹ naa ni tawọn.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Sẹnetọ Balogun ki i ba awọn agba ẹgbẹ ṣe pọ, o waa ro pe oun ni Gomina Makinde kan maa fun ni tikẹẹti pada lati dupo sẹnetọ fun saa keji laiṣe wahala. Bẹẹ, inu gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo dun si i bo ṣe jẹ pe Joseph Tegbe ni gomina fun ni tikẹẹti yẹn.
“Emi ati ọpọ ninu awa ti a n tẹle e (Balogun) ti pinnu pe a ko ni i tẹle e lọ sinu APC to lọ yẹn nitori gbogbo wa la fara mọ igbesẹ ti gomina gbe. A o le lọ sinu APC nitori a mọ pe pupọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ APC gan-an ni wọn maa dara pọ mọ PDP ko too dasiko idibo.”
Ta o ba gbagbe, laipẹ yii ni Sẹnetọ Balogun kede pe oun ko ṣe ẹgbẹ PDP mọ lẹyin to ti gbiyanju lati dupo aṣofin lẹẹkeji lorukọ ẹgbẹ oṣelu naa, ṣugbọn ti ko ri tikẹẹti ẹgbẹ ọhun gba, to jẹ pe agba oṣelu to ṣẹṣẹ ti inu ẹgbẹ APC dara pọ mọ PDP nni, Joseph Tegbe, ni kinni naa ja mọ lọwọ.