Mosunmọla Saka
Olori ijọ Citadel Global Community Church, Pasitọ Tunde Bakare, ti kede erongba rẹ lati dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ APC ninu eto idibo to n bọ lọdun 2023.
Ni gbọngan ayẹyẹ nla Musa Yar’adua, lo ti sọ eyi di mimọ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan-an, oṣu
Karun-un yii, l’Abuja.
Ọkunrin to dije dupo igbakeji aarẹ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ninu ẹgbẹ CPC to ti darapọ mọ APC bayii lasiko ibo gbogbogboo ọdun 2011 ti ṣeleri pe iṣejọba oun yoo yatọ, yoo si fi awọn
eeyan orilẹ-ede yii lọkan balẹ lori eto aabo.
Bakare sọ ọ di mimọ pe oun wa lara awọn ti wọn da ẹgbẹ oṣelu APC silẹ, oun si tẹnu mọ ọn pe oun ko figba kan ṣe ẹgbẹ mi-in ri yatọ si APC. O waa fi
da awọn ọmọ orilẹ-ede yii loju pe toun ba dori aleefa, eto ọrọ aje yoo gberu si i, lai fi ti ẹya kankan ṣe.
O ni, “Mo fa ara mi kalẹ gẹgẹ bii afara laarin Naijiria oni ati eyi ti ko ni aṣeti ninu.
‘‘Awọn eeyan Naijiria nilo ẹni to le mu ki alaafia wa laarin awọn oniruuru ẹya to wa nilẹ yii, eyi gan-an si ni ohun to jẹ mi logun ti mo fi fẹẹ jade gẹgẹ bii aarẹ lọdun to n bọ.’’