Faith Adebọla, Eko
Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un yii, awọn gende meji yii, Ayọ Taiwo, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, ati Jude Prince Ovat, ẹni ọdun mọkanlelogun, da ọlọkada kan duro, wọn ni ko gbe awọn lọ sibi kan, aṣe adigunjale gidi ni wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, to fọrọ yii lede ninu atẹjade rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, sọ pe, aago mọkanla alẹ ọjọ Aje naa lọwọ ba awọn afurasi mejeeji yii.
O ni iwadii ti wọn ṣe fihan pe niṣe ni Prince Ovat ati Chibuike Daniel ni ki ọlọkada naa gbe awọn lati Ọbalende lọ si Parkview Estate, to wa n’Ikoyi, nibi ti ẹni kẹta ti wọn jọ n ṣiṣẹ laabi lagbegbe naa, Ayọ Taiwo, ti n duro de wọn.
Bi ọlọkada naa ṣe n ja wọn silẹ, niṣe ni Chibuike fa irinṣẹ mẹkaniiki kan, irin ti wọn fi n tu taya mọto lo la mọ ọn lori lojiji, niyẹn ba ṣubu.
Oju ẹsẹ ni wọn ti ki ọkada ẹ mọlẹ, awọn mẹtẹẹta bẹ sori ẹ, ni wọn ba sa lọ, ṣugbọn awọn eeyan kan to n wo wọn lọọọkan ri ohun to ṣẹlẹ, wọn si ke sawọn ọlọpaa ikọ ayara-bii-aṣa RRS (Rapid Response Squad) to wa nitosi, bẹẹ lawọn ọlọpaa lepa wọn lọ, ọwọ si ba meji ninu wọn, pẹlu ọkada ti wọn ji, bo tilẹ jẹ pe ẹni kẹta sa lọ rau.
Nigba ti wọn ko wọn de teṣan, awọn afurasi adigunjale yii jẹwọ pe ọmọ tuntun ki i ṣe akọpa ajẹ fawọn, o ti pẹ tawọn ti n jale, ṣugbọn ọkada lawọn maa n ja gba ni tawọn. Wọn tun jẹwọ pe ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (N150,000) lawọn maa n ta ọkada kọọkan.
Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, CP Abiọdun Alabi, ti gbọ sọrọ yii, o si ti paṣẹ ki wọn taari awọn mejeeji yii si ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ wọn to wa ni Panti, ni Yaba, fun iwadii to lọọrin. Bakan naa lo ni ki wọn wa ẹni kẹta to sa lọ lawaari, ki wọn si tọpa awọn ti wọn n ra ẹru ole lọwọ wọn, lẹyin naa ni wọn maa foju bale-ẹjọ.