Faith Adebọla, Eko
Ọwọ ẹṣọ aabo ara ẹni laabo ilu, awọn sifu difẹnsi, ti ba ọkunrin ẹni ọdun mejilelaaadọta kan, Kabiru Abdullahi, ati ọrẹ ẹ ti wọn jọ huwa ọdaran, Alaaji Yawale, ẹni ọdun marundinlaaadọta. Ọmọ aladuugbo wọn ti ko ju ọmọọdun marun-un lọ ni wọn ji gbe, wọn yin in lọrun pa, wọn tun fi ẹtan gbowo lọwọ awọn obi ẹ.
Lasiko ti wọn n ṣafihan awọn ọdaju amookunṣika ẹda naa lolu ileeṣẹ NSCDC to wa niluu Bauchi, nipinlẹ Bauchi, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un yii, Kọmandaati awọn Sifu Difẹnsi ipinlẹ naa, Nurudeen Abdullahi, sọ pe iwaju ile awọn obi ọmọbinrin naa lawọn afurasi ọdaran yii ti ji i gbe lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, to kọja, lasiko tawọn obi ọmọ naa ko si nile.
O ni iwadii ti wọn ṣe fihan pe nigba ti wọn gbe ọmọbinrin naa de itosi afara odo kan ni wọn yin in lọrun to fi ku, wọn si di oku ẹ sinu apo idọhọ kan to wa lọwọ wọn.
Lẹyin naa ni wọn lọọ sin oku rẹ si aarin kiṣinni ile ti Kabiru n gbe, wọn si pe baba ọmọbinrin naa lori aago, wọn sọ fun un pe ọmọbinrin ẹ wa lọdọ awọn, awọn ti ji i gbe, miliọnu kan Naira lawọn si maa gba lati tu u silẹ, ṣugbọn lẹyin ti ẹbẹ ati idunaa-dura pọ, wọn gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (N150,000) lọwọ awọn obi ọmọ naa, abẹ igi ọsan tanjalo kan ni wọn gbowo naa si fun wọn, ṣugbọn wọn ko ri ọmọ ti wọn tori ẹ sanwo ọhun, tori wọn ti pa a.
Nurudeen ni bi wọn ṣe fọrọ yii to awọn leti ni awọn ọtẹlẹmuyẹ ti bẹrẹ iwadii, abọ iwadii naa ni wọn fi ri awọn afurasi mejeeji mu. Nigba ti wọn yẹ ile Kabiru wo, wọn ri oku ọmọ naa nibi to sin in si, wọn hu u, wọn si gbe e lọ sọsibitu jẹnẹra to wa ni Bauchi. Wọn tun ba ẹgbẹrun mejilelogoji Naira (N42,000), ati igba ayederu owo dọla ($200), kaadi siimu MTN meji, ati awọn kọkọrọ mọto oriṣiiriṣii.
Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ yii.