Gbenga Amos, Abẹokuta
Baale ile kan, Dare Quadri, ti n kawọ pọyin rojọ nile-ẹjọ Majisreeti to wa ni Iṣabọ, l’Abẹokuta, latari bo ṣe jẹwọ pe loootọ loun laṣepọ pẹlu ọmọ bibi oun, ọmọọdun mẹtala pere, o ni etutu lati kuro lẹgbẹ awo toun wa, lo jẹ koun ṣe bẹẹ.
Nigba ti igbẹjọ bẹrẹ lori ẹsun naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, afurasi ọdaran naa jẹwọ ni kootu pe loootọ loun laṣepọ pẹlu ọmọ oun, ti wọn forukọ bo laṣiiri naa, ṣugbọn o ni oun kan fọwọ pa a lọmu ni, oun ko ba a sun gidi.
Ọkunrin ti wọn lo n ṣiṣẹ ijọba, nileeṣẹ akolẹta (NIPOST) sọ pe oun o kan ṣadeede ki ọmọ oun mọlẹ o, o ni tori oun fẹẹ kuro lẹgbẹ awo kan toun wa ni, ohun ti wọn si ni koun ṣe niyẹn, ati pe toun o ba ṣe e, awọn ọmọ oun maa ku.
Ninu alaye ti iyawo afurasi naa ṣe lori ọrọ yii, Abilekọ Bukọla Quadri, sọ pe loorekoore loun maa n ba wọn ọmọbinrin meji toun bi sọrọ, toun maa n yẹ wọn, toun si maa n sọ ewu to wa ninu ibalopọ ti ko tọ fun wọn.
“Loṣu Disẹmba, ọdun 2021, nigba ti mo n ba awọn ọmọ naa sọrọ, mo ṣakiyesi pe nnkan kan ti ṣẹlẹ si eyi to dagba ju ninu wọn, mo si bi i leere, esi to fun mi ni pe ‘Dadi ni o’. Mo ni Dadi wo, o ni Dadi wa.
Lẹyin ti mo lu u lẹnu gbọrọ, o si ṣalaye bi baba ẹ ṣe maa n fipa ba a lo pọ, to tun maa n ṣe oriṣiiriṣii iwa ti o tọ pẹlu ẹ lasiko ibalopọ naa. O ni baba oun maa n sọ foun pe oun maa fi i ṣe iyawo keji to ba ya. O ni to ba ti ba oun laṣepọ tan, o maa paṣẹ foun ki oun tete lọọ fọ atọ to da sara oun kuro ni tọilẹẹti, oun si maa n ṣe bẹẹ.
Niṣe lori mi kọkọ fo lọ. Gbogbo asiko ti eyi n ṣẹlẹ, mo wa lori idubulẹ aisan, oogun oorun to lagbara gidi si ni mo n lo nigba yẹn, ti mo ba ti jẹun tan ti mo si lo o, mo maa sun lọ fọnfọn ni.
“Mo ko ọkọ mi loju, o ni ki n pa oun sile, ki n ma pariwo sita. O loun wa ninu ẹgbẹ awo kan, oun si fẹẹ kuro, ṣugbọn wọn ni ayafi ti oun ba ba eyi o dagba ninu ọmọ bibi oun laṣepọ, aijẹ bẹẹ, gbogbo ọmọ wa lo maa ku.
Agbefọba lati ẹka ti wọn ti n gba awọn adajọ lamọran, DPP, ni afurasi naa ti jẹwọ fawọn nipa ibalopọ to n ṣe.
Adajọ paṣẹ ki wọn da ọkunrin naa pada sẹwọn, titi di ọjọ karun-un, oṣu Keje, ọdun yii.