Ọwọ tẹ Peter, olori awọn ẹgbẹ okunkun ni Mowe

Gbenga Amos, Abẹokuta

Peter Christian, gende kan to ti sọ ara ẹ di ẹrujẹjẹ ni Mowe, ti ko jẹ ki wọn le sun oorun asunwọra, ti ko sakolo ọlọpaa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un yii.
Iwaju otẹẹli kan, nibi to ti n ṣe faaji ara ẹ, ni wọn ti ri i lọsan-an ọjọ naa. CSP Fọlaṣade Tanaruno to jẹ DPO teṣan Mowe loun atawọn ẹmẹwa ẹ n ṣe patiroolu agbegbe Mowe si Ọfada, ni wọn ba taju kan-an ri afurasi ọhun, o gbe baagi kekere kan kọrun laduugbo Olororo, ẹwu jalamia funfun kan lo wọ, kia ni wọn ti lọọ mu un.
Nigba ti wọn yẹ inu baagi ọrun ẹ wo, ibọn oloju-meji pompo kan lo wa nibẹ, ọta ibọn kun inu ibọn naa tẹmu-tẹmu.
Afurasi ọdaran yii wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n da omi alaafia agbegbe Mowe ru, wọn loun lolori ẹgbẹ okunkun kan nibẹ, o si ti pẹ tawọn ọlọpaa ti n wa a, to n sa pamọ fun wọn.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi ni awọn ti taari afurasi naa si ẹka ti wọn ti n ṣewadii awọn ẹlẹgbẹ okunkun l’Eleweeran, Abẹokuta, gẹgẹ bi Kọmiṣanna wọn, CP Lanre Bankọle, ṣe paṣẹ.

Leave a Reply