Faith Adebọla
Bo tilẹ jẹ pe o ti pa ọrọ naa rẹ lori ikanni ayelujara, titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n fi ibinu wọn han si Igbakeji olori orileede wa tẹlẹ, Alaaji Atiku Abubakar, latari ọrọ to fi lede soju opo tuita ati fesibuuku rẹ, lori ẹrọ lori bawọn eeyan kan ṣe fọgi mọ akẹkọọ-binrin ileewe olukọni to wa ni Sokoto, Deborah Samuel, lori titi to fi ku, ti wọn si tun dana sun oku ẹ, wọn lo sọrọ abuku si Anọbi Muhammed.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejila, oṣu Karun-un yii, niṣẹlẹ ọhun waye nileewe awọn olukọni ti Shehu Shagari College of Education, to wa niluu Sokoto, nipinlẹ Sokoto.
Ninu fọran fidio to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara nipa iṣẹlẹ ọhun, a ri ọgọọrọ awọn gende, akẹkọọ ẹlẹgbẹ oloogbe ọhun ninu aṣọ kaba pupa to wọ, ti wọn n fọgi mọ oku rẹ lẹyin ti wọn ti foko fọ ọ lori tan, lẹyin naa ni wọn ko aloku taya ọkọ le e lori, ti wọn si dana sun un.
Ọkan ninu awọn apaayan ẹda naa n sọrọ fatafata ninu fidio ọhun pe oun loun pa a, o lo sọrọ abuku si Anọbi Mohammed lawọn ṣe pa a. Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Sokoto ni niṣe lawọn akẹkọọ to n ṣe bii ayiri ọhun fi agidi yọ akẹkọọ-binrin naa jade ninu yara sikiọriti ti wọn daabo bo o si, ki wọn too kọ lu u, ti wọn si pa a.
A gbọ pe ọrọ ariyanjiyan kan lo waye laarin oloogbe naa ati akẹkọọ ẹlẹgbẹ rẹ kan, lasiko ariyanjiyan naa ni wọn fẹsun kan Deborah pe ọrọ to sọ ko ṣapọnle Anọbi, lawọn akẹkọọ yooku ba fabinu yọ, titi ti wọn fi gbẹmi rẹ.
Bi iṣẹlẹ ṣe waye, tawọn eeyan si n bẹnu atẹ lu iwa buruku ati idajọ ko-duro-gbẹjọ ti wọn ṣe fọmọbinrin arẹwa yii, bẹẹ ni Alaaji Atiku Abubakar, ọkan lara awọn ondije funpo aarẹ ilẹ wa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP kọ ọ sori awọn ikanni rẹ pe: “Ko si alaye to ba idajọ ododo mu kan teeyan le ṣe lori iku buruku ti wọn fi paayan yii. Wọn ṣika pa Deborah Yakubu ni, gbogbo awọn to si lọwọ ninu iku rẹ gbọdọ jiya ẹṣẹ wọn. Mo ba awọn mọlẹbi ati ọrẹ oloogbe naa kẹdun.” Ọrọ naa ko ju bẹẹ lọ.
Ṣugbọn loju-ẹsẹ lawọn agbawere-mẹsin ẹda kan ti bẹ sori ẹrọ ayelujara Atiku, ti wọn si bẹrẹ si kọ ọrọ idunkooko-mọni ṣọwọ si i, wọn lawọn o nifẹẹ si bi ko ṣe sọrọ ta ko ifabuku-kan-Anọbi ti wọn fẹsun rẹ kan oloogbe ọhun, wọn si kọ ọ sibẹ pe awọn le ṣe akọlu soun naa, tabi ki wọn gbegi dina erongba rẹ lori ipo aarẹ to fẹẹ dije fun.
O jọ pe ọrọ ihalẹ-mọni yii lo mu Alaaji Abubakar pa ọrọ ibanikẹdun to ti kọ tẹlẹ naa rẹ, o si gbe ọrọ mi-in sori opo ayelujara mi-in lorukọ ara rẹ, o loun o mọ ohunkohun nipa ọrọ akọkọ naa, oun ko loun kọ ọ, oun o si ran ẹnikẹni lati ba oun kọ ọ.
Ṣugbọn niṣe ni eyi tubọ mu kawọn ọmọ Naijiria binu si baba naa, wọn ni ojo ati alabosi ẹda kan ni, ati pe ohun to ṣe yii fihan pe iru ẹ kọ lo yẹ ki wọn dibo yan sipo aarẹ, tori o ti fihan pe ki i ṣe ẹni to le sọrọ ti yoo duro ti ọrọ rẹ, bẹẹ ni ki i ṣe ẹni tawọn le gbara le fun ohun to ba sọ.
Ẹnikan kọ ọ sibẹ pe: “Ha, ẹ wo beeyan ṣe n ko ọrọ ẹ jẹ. Awọn kan si ro pe ọkunrin yii maa san ju Buhari lọ ṣa! Eyi ti fihan pe inu iṣoro gidi la wa lorileede yii pẹlu iru awọn aṣaaju bii eyi.”
Ẹlomi-in tun kọ tiẹ pe: “Ẹ gbọ ọrọ ailọwọ ti baba yii n sọ. Iwọ funra ẹ lo kọ nnkan, o tun waa n sọ fun wa pe wọn kọ ọ laigba aṣẹ lọwọ ẹ ni, tori o fẹẹ fi wa rugbo, abi? Niṣe ni ki iwọ Waziri ilu Adamawa yii lọọ wabikan jokoo si o, ko o dakẹ jẹẹ, ko o si tọrọ aforijin lọwọ Ọlọrun Ọba fun iru aṣiṣe too ṣe yii.”
Bayii lawọn eeyan koro oju si iwa ti Atiku hu ọhun.