Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Tijani Olagunju, ti jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe eeyan mẹta ni o ti pa ko le gba igbega ipo keji ninu ẹgbẹ okunkun lẹka tiluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.
Agbegbe Agbo-Ọba, niluu Ilọrin, lawọn ọlọpaa ti mu ọmọkunrin naa fẹsun idigunjale ati ki kopa ninu ẹgbẹ okunkun.
Tijani, jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe ni ọjọ kọkanlelogun, osu kẹrin, ọdun 2022, o pa arakunrin kan smaila Alabi a.k.a Abbey, ni agbegbe Agbo-Ọba, niluu Ilọrin, pẹlu ibọn ilewọ kekere kan. Bakan naa o tun yinbọn pa ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Emmanuel, to jẹ akẹkọọ ileewe giga Fasiti, Ilọrin, ninu osu keji, ọdun yii. O tẹsiwaju pe ibọn baba rẹ to doloogbe lo n lo fi ṣe isẹ buruku naa. O fi kun un pe eeyan mẹta to pa lo fi jẹ ọga patapata.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa, nipiinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, sọ pe iwadii fi han pe ọkan lara ọmọ ẹgbẹ Ẹyẹ ni Tijani, ti wọn si ti n sa gbogbo ipa wọn lati mu awọn ọmọ ẹgbẹ yooku.