Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Laafin Ẹmia Ilọrin, Alaaji Ibrahim Zulu Gambari, ni Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajọ, ti sọ pe oun loun kun oju oṣuwọn ju, oun ni imọ, oun si tun ni iriri ju lati gba ipo lọwọ Ọgagun Muhammadu Buhari ninu gbogbo awọn oludije ninu eto idibo ọdun to n bọ.
Ọṣinbajọ sọrọ yii lọjọ, Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lakooko to ṣabẹwo sawọn ọmọ ẹgbẹ Onigbaalẹ nipinlẹ Kwara lati beere fun atilẹyin wọn lakooko eto idibo abẹle ẹgbẹ naa to n bọ lọna.
Ọṣinbajọ ni iriri toun ri laarin ọdun meje toun fi ṣe ijọba pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari fi oun lọkan balẹ pe oun yoo gba ipo akoso ijọba lọwọ Buhari, lọdun 2023.
O juwe ara rẹ gẹgẹ bii ọlọgbọn ati oloye, to si ni imọ pupọ nipa eto ati bi ọjọ iwaju Naijiria yoo ṣe dara. O ni ti oun ba wọle gẹgẹ bii aarẹ, oun yoo wa atunṣe si iṣoro to n dojukọ orilẹ-ede Naijiria, ni pataki ju lọ, eto aabo ati ọrọ aje to dẹnu kọlẹ.
O ṣalaye pe didije ti oun fẹẹ dije wa lati ṣiṣẹ sin awọn ọmọ orilẹ-ede yii ni. O fi kun un pe iriri ti oun ti ni gẹgẹ bii Igbakeji Aarẹ ati lakooko ti oun ṣe adele fun Aarẹ ti fi oju oun si awọn anfaani to wa lorilẹ-ede yii.
O ni oun ti ṣetan lati tun orile-ede yii sọ bii ẹni sọ igba, ki idagbasoke le ba awọn ọmọ Naijiria.
O juwe Aarẹ Buhari to ti ṣiṣẹ labẹ rẹ fun ọdun meje gẹgẹ bii oloootọ ati oniwa tutu eniyan. O ni iriri ati ẹkọ ti oun ri labẹ Buhari lo mu oun jade lati dupo aarẹ naa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘‘Mo fẹẹ sọ fun yin pe didije ti mo n dije fun ipo aarẹ fi han pe Ọlọrun Ọba ti fun mi ni anfaani lati fi ara mi silẹ lati sin orilẹ-ede mi. Lati ọdun meje ti mo ti wa lori ipo gẹgẹ bii Igbakeji Aarẹ, mo ti ṣoju Aarẹ lọpọlọpọ igba, bakan naa ni mo ti ni anfaani lati wa nidii eto iṣejọba ati bi alaafia yoo ṣe de ba orilẹ-ede yii ni gbogbo ẹka.
“Mo ti ni anfaani lati ṣiṣẹ labẹ Aarẹ to loye, to si ni erongba bi orilẹ-ede yii yoo ṣe dara, bẹẹ lo tun fun mi ni anfaani lati jẹ ki n mọ awọn iṣoro to n dojukọ orilẹ-ede Naijiria ati awọn orilẹ-ede miiran.’’
Gomina Abdulrahman Abdulrazak, ninu ọrọ ti ẹ sọ pe ọrẹ ipinlẹ Kwara ni Ọṣinbajo, tori pe o ti wa si Kwara lati waa ṣe ifilọlẹ eto iranwọ owo isowo fun awọn ti ko rọwọ họri nipinlẹ Kwara. Lara awọn to tẹle gomina lọọ pade Ọṣinbajo ni Igbakeji Gomina, Kayode Alabi, Abẹnugan ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara, Yakubu Danladi, sẹnetọ to n ṣoju Ariwa ipinlẹ Kwara, eyi to n ṣoju Guusu to fi mọ alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa, Sunday Fagbemi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bakan naa, Ẹmia ilu Ilọrin, Alaaji Ibrahim Zulu Gambari, sọ pe Yẹmi Ọṣinbajo ti ni awọn akọsilẹ rere lati di Aarẹ lọdun 2023, to si ni o le tukọ Naijiria de ebute ogo.