Monisọla Saka
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ileewe giga fasiti, ASUU atawọn ẹgbẹ yooku ti jẹ ko di mimọ pe awọn atijọba apapọ ko fẹnu ko rara, bẹẹ ni ko si adehun tabi asọyepọ laarin awọn to le mu ki awọn da iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ duro.
Gbogbo ileewe giga fasiti to jẹ tijọba jake-jado orilẹ-ede yii ni wọn ṣi wa lori ija fun ẹtọ wọn lọwọ ijọba apapọ.
Ta o ba gbagbe, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2022, ta a wa yii ni ẹgbẹ ASUU gun le iyanṣẹlodi, ti awọn JAC, iyẹn agbarijọpọ igbimọ awọn oṣiṣẹ to n ja fẹtọọ wọn naa si bẹrẹ lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, bakan naa.
Idi iyanṣẹlodi ti awọn ajọ wọnyi gun le ni ẹtọ wọn ti wọn n beere fun lọwọ ijọba, atunṣe si awọn ileewe, ati imuṣẹ adehun to wa laarin awọn atijọba apapọ lati ọdun 2009 si 2020.
Adari apapọ fun ẹgbẹ ASUU, Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke ati Ọgbẹni Mohammed Ibrahim to jẹ adari fun ajọ JAC, ṣalaye pe ijọba apapọ atawọn tọrọ kan nidii eto ẹkọ, to fi kan awọn aṣaaju ẹsin, ni wọn ti ba ẹgbẹ mẹrẹẹrin tọrọ kan yii ṣepade, ṣugbọn awọn ko fẹnu ọrọ jona sibi kan gidi.
Minisita feto igbanisiṣẹ ati iṣẹ ṣiṣe, Sẹnetọ Chris Ngige ni wọn lo sọrọ lopin ọsẹ yii pe, “A sọ ọpọlọpọ awọn ọrọ to da mi loju pe yoo so eeso rere, a ti foju ṣunnukun wo awọn ọrọ naa, a si ti fẹnu ko lori awọn adehun kan, eyi ti yoo ṣe gbogbo awa tọrọ kan lanfaani”
Nigba ti Osodeke maa sọrọ, o ni irọ nla to jinna si ootọ ni ohun ti Ngige sọ lẹyin ipade tawọn ṣe pe, ninu ọsẹ yii ni awọn fagi le iyanṣẹlodi tawọn gun le, o ni ọrọ oṣelu lo fi bọ ọ, pe ko sohun to jọ bẹẹ.
Osodeke ni, “Awa o mọ si ọrọ a n dawọ iyanṣẹlodi duro o. Loootọ la ṣepade, ṣugbọn aabọ ipade naa ko daa, nitori ko si ohun kan dan-in dan-in laarin awa atijọba. Gẹgẹ bi a ti ṣe sọ tẹlẹ, awa o fẹ adehun, bi kii ṣe pe ki wọn ṣe ohun ti wọn n sọ lẹnu ka ri i, nigba ti wọn ba ṣe ohun ta a fẹ, ti wọn mu adehun ṣẹ, a o lọọ ba awọn ọmọ ẹgbẹ wa, ṣugbọn nitori ta a ti mọ ete wọn latẹyinwa, a ti mọ pe wọn o ni i ṣe nnkan kan”.
Ibrahim naa kin ọrọ ti Osodeke sọ lẹyin, o ni, awọn o sọrọ dida iyanṣẹlodi duro bayii bo ti wu ko mọ.