Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe awọn ọlọpaa ti tu Oludasilẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi Hamzat ti wọn gbe lọ si akata wọn silẹ.
Ninu atejade kan to tẹ ALAROYE lọwọ, eyi ti Adebayọ Yousuph Grey, fọwọ si lorukọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ni wọn ti sọ pe ‘‘Wọn ti yọnda Oriyọmi Hamzat ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. Eyi waye lẹyin ti wọn fun un ni beeli, ti ajọsọpọ ọrọ si waye laarin awọn alaṣẹ kan ati lọọya rẹ, paapaa ju lọ lori iwe ẹsun ti Raheem Adedoyin kọ nipa rẹ, ni wọn fa a le agbẹjọro rẹ lọwọ.
‘‘Gẹgẹ bi a ṣe sọ lanaa, ko si igba kan ti Oriyọmi lo ẹrọ ayelujara lati dunkooko tabi lati fi dẹruba ẹnikẹni, bẹẹ ni ko si igba kankan ti wọn fiwe pe e to kọ lati jẹ ipe awọn ọlọpaa. Idi ti wọn fi n pa iru irọ bayii mọ ọn ni ko ye ẹnikẹni.
‘‘A wa n fi asiko yii dupẹ lọwọ gbogbo ẹyin ọmọ Naijiria tẹ ẹ jade, tẹ ẹ sọrọ sita pe ki wọn yọnda Oriyọmi lahaamọ. Idasilẹ naa ki ba ti ya bo ṣe ya yii bi ko ṣe awọn ọrọ ati ariwo ti ẹ pa.
‘‘Bakan naa la dupẹ lọwọ awọn to ṣe iwọde niluu Ibadan lori ọrọ yii, ẹgbẹ awọn akọroyin, awọn ileeṣẹ iroyin kaakiri, awọn ọmọ Naijiria nile loko ati lẹyin odi. Bakan naa la mọ riri agbẹjọro wa, Adekunle Ridwan fun akitiyan rẹ.
A o maa fi gbogbo rẹ to yin leti bo ba ṣe n lọ si.’’