Faith Adebọla, Eko
Pẹlu bi ojo ikini ku oriire ṣe n rọ sori Alaaji Atiku Abubakar, ẹni ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ṣẹṣẹ yan lati dupo aarẹ orileede yii lorukọ ẹgbẹ wọn ninu eto idibo ọdun 2023, Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri, to tun jẹ ondije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti fi ikini tiẹ naa ṣọwọ si Atiku, o loun ba a yọ, oun si n foju sọna lati ba a ta kangbọn lasiko idije funpo aarẹ laipẹ.
Ọrọ yii wa ninu atẹjade kan ti Adari apapọ fẹgbẹ APC naa fi lede loru ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, kete ti Atiku jawe olubori nibi eto idibo abẹle ti PDP ṣe l’Abuja, nibi ti wọn ti yan an gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ wọn.
Tinubu ni aṣeyege Alaaji Atiku ko ya oun lẹnu, tori oun ti mọ Atiku tipẹ, ẹni to ni iriri to pọ nipa eto oṣelu ati iṣakoso ni, agba ọjẹ si ni nidii ọrọ ilu, o ni eeyan to nifẹẹ Naijiria denudenu ni, ẹni to si nifẹẹ ilọsiwaju orileede yii ni pẹlu.
“Inu mi dun si bi Alaaji Atiku ṣe jawe olubori gẹgẹ bii oludije funpo aarẹ ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ PDP ti wọn ṣe tan yii. Mo n foju sọna lati ba a figa gbaga gẹgẹ bii oludije ẹlẹgbẹ mi lasiko idibo to n bọ.
“Mo ti mọ igbakeji aarẹ yii tipẹ gẹgẹ bii eekan oloṣelu, ati ẹni to nifẹẹ Naijiria dọkan, mo mọ pe o gbagbọ ninu iṣọkan ati ilọsiwaju orileede wa ọwọn yii, daadaa.
“Bi asiko eto idibo ṣe n wọle de, mo rọ oludije ẹgbẹ PDP ati awọn ti wọn fẹẹ ta ayo oṣelu loriṣiiriṣii ninu awọn ẹgbẹ oṣelu yooku, pe ka jọ yago fun oṣelu ẹtanu, onitẹmbẹlẹkun ati ija.
“Ẹ jẹ ki awọn eto ipolongo wa da lori alaafia ati ọrọ gidi to jẹ Naijiria logun. Asiko idibo gbọdọ jẹ asiko ti oniruuru ero to mọgbọn dani, ọrọ laakaye, aba ati imọran to le ṣe ilu lanfaani maa gbode kan.
“O kan jẹ pe, fun ẹgbẹ oṣelu PDP, oludije wọn maa ni lati rojọ, ẹnu ẹ aa fẹrẹ bo, tori o maa ṣalaye bi wọn ṣe fi ọdun mẹrindinlogun ṣofo lai si nnkan aritọkasi gidi kan faraalu.
Amọ sibẹ, mo ba Atiku yọ, mo si ki i kuu oriire ijagunmolu yii o.”
Bẹẹ ni Tinubu sọ.