Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Odu ni Onidaajọ Ọlamide Oloyede, obinrin adajọ kan to kọ lẹta sijọba Gomina Arẹgbẹṣọla lọdun 2016 lori iya to n jẹ awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn oṣiṣẹ-fẹyinti, ki i ṣe aimọ foloko.
Gbogbo agbaye lo mọ nigba naa pe wọn da a duro lẹnu iṣẹ adajọ lẹyin to kọ lẹta naa, ṣugbọn ni bayii, igbimọ to n ṣakoso ẹka eto-idajọ lorileede yii (National Judicial Commission) ti fun un niwee pe ko pada sẹnu iṣẹ bayii.
Gẹgẹ bi Alaroye ṣe gbọ, ninu ipade ti ajọ NJC ṣe lọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun yii, lẹyin ti ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Abuja ti da Oloyede lare, ni wọn ti pinnu lori igbesẹ naa pe ko pada sẹnu iṣẹ.
Lẹyin aṣẹ NJC yii, Oloyede ko ri iwe kankan lati ti ipinnu yii lẹyin, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni igbimọ to n ri si ẹka eto-idajọ nipinlẹ Ọṣun too fun un ni lẹta.
Wahala Onidaajọ Oloyede bẹrẹ lọdun 2016, nigba to kọwe sileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun lati yẹ idi Gomina Arẹgbẹṣọla wo pẹlu oniruuru ẹsun to fi kan an sinu lẹta naa.
Ohun to ṣe yii lo mu ki awọn kan ti wọn pe ara wọn ni Osun Civil Societies Coalition, kọwe ẹsun si ajọ NJC pe ki wọn fi ọwọ osi juwe ile fun un nitori adajọ ko gbọdọ gbe si ẹnikẹni lẹyin, ko si gbọdọ da si ọrọ to ba n ṣẹlẹ layiika rẹ.
Bayii ni Oloyede, nipasẹ agbẹjọro rẹ, J. Daudu, fori le ile-ẹjọ giga ijọba apapọ niluu Abuja, ti ile-ẹjọ si da a lare loṣu Kẹfa, ọdun 2021, ko too di pe awọn NJC gba a pada loṣu Karun-un ọdun yii.
Alaroye gbọ pe ile-ẹjọ giga ijọba ipinlẹ Ọṣun kan to wa lagbegbe Ileṣa, lobinrin adajọ ti awọn oṣiṣẹ-fẹyinti nigba naa fun ni apejẹ ‘Mọremi’ wa bayii.
Amọ ṣa, ẹgbẹ kan, The Osun Mastermind, ti gboriyin funjọba ipinlẹ Ọṣun pẹlu igbesẹ gbigba Onidaajọ Oloyede pada si aaye rẹ, bo tilẹ jẹ pe ‘iwa-ọdaju’ naa ti pẹ ju, sibẹ, wọn ni Oyetọla ṣe daadaa pẹlu bo ṣe tẹle aṣẹ ile-ẹjọ.
Alakooso ẹgbẹ naa, Dokita Wasiu Oyedokun-Alli, waa rọ ijọba lati tẹsiwaju ninu ilana idajọ ododo ati ti alaafia to gun le.