Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọpọ awọn to wa nibi ti afurasi ajọmọgbe kan, Adeọla Ọmọniyi, ti n ka lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, ni wọn yanu ti ati pa ẹnu wọn de pada si di iṣoro nla fun wọn latari awọn ọrọ kayeefi to n jade lati ẹnu obinrin ẹni ọdun mejilelogun ọhun.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ ninu ọrọ ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ba awọn oniroyin sọ lasiko ti wọn n ṣafihan afurasi ọhun atawọn ọdaran mi-in ni olu ileeṣẹ wọn l’Akurẹ. O ni ọjọ kin-in-ni, oṣu Keje, ọdun ta a wa yii, lọwọ awọn eeyan kan tẹ Adeọla pẹlu ọmọ ọdun marun-un kan to ji gbe laarin igboro Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo.
O ni iya to bi iya ọmọ naa lo ran an niṣẹ lọjọ yii ti afurasi ajọmọgbe ọhun fi pade rẹ lọna, ibi to ti n fa ọmọ ọlọmọ lọwọ lọ sibi tawọn eeyan ko ti ni i ri i lo ni ẹnikan to mọ ọmọdebinrin naa ti pariwo le e lori.
O ni wọn gbiyanju ati mu afurasi ọhun ti wọn si lọọ fa a le awọn ọlọpaa ilu Ọrẹ lọwọ.
Ninu iwadii lo ni Adeọla ti jẹwọ fawọn pe adugbo Okeasa, ni Ilu Tuntun, nijọba ibilẹ Okitipupa, loun n gbe, ati pe baba to bi oun lẹni to maa n gba awọn ọmọ ọlọmọ toun ba ti ji gbe lọwọ oun, to si maa n fun oun ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira lori ọmọ kọọkan.
Ọrọ ti ọmọbìnrin ti wọn fẹsun kan ọhun ba awọn oniroyin sọ lasiko ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo ko fi bẹẹ yatọ rara si ohun to ti kọkọ sọ fawọn ọlọpaa.
Eyi ni alaye to ṣe fun wa ninu ifọrọwerọ ta a ṣe pẹlu rẹ:
Iṣẹ ajọmọgbe ni mo n ṣe loootọ, o si ti to bii ọdun meji sẹyin ti mo ti wa lẹnu iṣẹ naa, bẹẹ ni awọn ọmọ keekeekee ni mo saaba maa n ji gbe.
Ẹẹmeji ni mo ti ji ọmọ gbe, Ilu Tuntun, nibi ti mo n gbe ni mo ti ji ti akọkọ lọdun 2021, mo ji ọmọ keji gbe ni Ilowo, lọdun ta a wa yii, ọmọ kẹta ni mo fẹẹ gbe ti ọwọ fi tẹ mi.
Nigbakuugba ti mo ba ti ri ọmọ ọlọmọ gbe, ọdọ baba mi ni Igbotako, ni mo maa n ko wọn lọ, nitori pe oun lo bẹ mi lọwẹ lati maa ji ọmọ ọlọmọ gbe wa foun.
Mi o le sọ ni pato ohun to n fi awọn ọmọ naa ṣe, temi ni ki n ti ji ọmọ gbe, ko si fun mi lẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira lori ọmọ kọọkan ti mo ba ti ji gbe.
Ko sohun ti mo n fi owo naa ṣe ju pe ki n fi jẹun, ki n si tun fi tọju ara mi lọ. Ọmọkọmọ ti mo ba ti pade lọna lai si iya rẹ nibẹ ni mo maa n raaye ji gbe, ṣe ni ma a kọkọ da wọn duro, ti ma a si beere ibi ti wọn n lọ, lẹyin eyi ni ma a fa wọn lọwọ, ti n oo si maa mu wọn lọ.
Nigba to n fesi lori awọn ẹsun ti ọmọ rẹ fi kan an, Ọgbẹni Ọmọniyi ni funfun lọwọ oun mọ lori awọn ẹsun naa, ati pe ko si ọrọ ma-jẹ-a-gbọ kankan laarin oun ati ọmọ oun.
O ni oun mọ pe ara ọmọ oun ko ya pẹlu aisan ọdẹ ori to ti n yọ ọ lẹnu, leyii to mu ki o pada wale nihooho ọmọluabi lati ipinlẹ Eko to wa iṣẹ aje lọ.
O ni oun gbiyanju ati gbe e lọ sile-ijọsin kan, nibi ti wọn ti gba ẹgbẹrun lọna ọgọrin Naira lọwọ oun gẹgẹ bii owo itọju rẹ.
O ni oun ti pasitọ to n tọju rẹ kọkọ sọ foun ni pe ara rẹ ti n ya diẹdiẹ, afigba ti ojisẹ Ọlọrun naa tun pe oun pe Adeọla ti sa kuro ni ṣọọsṣi tí wọn ti n tọju rẹ.
O ni oun ko laju oun ri i lati bii oṣu mẹfa sẹyin to ti sa lọ, ko too di pe o waa ko awọn ọlọpaa lẹyin waa ka oun mọle laipẹ yii pe oun loun gbe ọmọ ọlọmọ to n ji gbe fun.
Ọdunlami ti ni awọn ti ṣetan ati ko baba ati ọmọ naa lọ si kootu lẹyin ti iwadii awọn ba pari.