Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yinbọn pa Isiaka n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yinbọn pa akẹkọọ yunifasiti kan Mohammed Isiaka, ẹni ọdun mẹtalelogun, lagbegbe Akerebiata, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro Ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ọlasunkanmi Ajayi, fi sita lọjọ Iṣẹgun, lo ti sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa gba ipe lati agbegbe Akerebiata, niluu Ilọrin, pe awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ti yinbọn mọ Mohammed Isiaka, ti wọn si gbe e lọ si ileewosan ikọsẹ iṣegun Fasiti Ilọrin, ni Oke-Oyi, niluu Ilọrin, fun itọju to peye, sugbọn ti ọmọkunrin naa pada ku. O tẹsiwaju pe aya ni wọn ti yin in nibọn, eyi lo mu ko tete ku.

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ naa, CP Tuesday Assayomo, ti paṣẹ pe ki wọn ṣe iwadii lori iṣẹlẹ naa. O rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara, paapaa ju lọ, awọn to n gbe ni agbegbe Akerebiata, ki onikaluku pada sibi kara-kata wọn. O ṣeleri pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo pese aabo to peye fun wọn, ti wọn yoo si wa awọn afurasi ọdaran naa lawari, ti gbogbo wọn aa foju wina ofin.

Leave a Reply