Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Pẹlu bi awọn esi idibo ti n jade, o jọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji ni wọn n lera wọn lere, bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti n fi ibo to pọ diẹ ju ẹgbẹ APC lọ ninu awọn eyi ti wọn ti ka.
Ṣugbọn nitori pe awọn esi idibo mi-in ṣi n wọle, ko sẹni to ti i le sọ pe ibi bayii ni esi idibo naa yoo fori sọ. Tabi pe ẹni bayii ni yoo gbe igba oroke.
Bo tilẹ jẹ pe gbajumọ olorin nni, David Adeleke, ti gbogbo eeyan mọ si Davido, to jẹ ọmọ ẹgbọn Ademọla Adeleke toun naa jẹ oludije labẹ asia ẹgbẹ PDP ti n sọ pe o ti n foju han pẹlu awọn esi idibo to n wọle pe ẹgbẹ PDP yoo rọwọ mu ninu eto idibo naa.
Lori ikanni twitter rẹ ni Davido gbe e si pe ẹkọ ti n ṣoju mimu fun ẹgbẹ PDP nibi eto idiboto n lọ lọwọ yii, to si rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ki wọn ma ṣe kuro ni ibudo idibo, ki wọn duro ti ibo wọn.
Davido ni ki wọn ma wo ti ojo to n rọ, o ni ninu ojo naa ni awọn yoo ti ṣe ajọyọ, ṣugbọn ki wọn kọkọ duro ti ibo wọn na.