Awọn ọlọpaa ti mu Raṣidi Ọkọ’lu, ogbologboo tọọgi to n yọ awọn eeyan ilu Ẹdẹ lẹnu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lẹyin oṣu marun-un ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti kede pe awọn n wa ogbologboo tọọgi kan to fi ilu Ẹdẹ ṣebugbe, Rasheed Hanmed, ọwọ ti tẹ ẹ laaarọ ọjọ Aiku, Sannde.

Rasheed, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Raṣidi Ọkọọlu ni ọwọ tẹ ni nnkan bii aago mẹrin idaji niluu Oṣogbo tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ọṣun.

Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n gbogun ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, Anti-Cultism Unit, ni wọn mu ọmọkunrin to ti di ẹrujẹjẹ fawọn eeyan ilu Ẹdẹ naa.

Ninu oṣu Kẹta, ọdun yii, ni awọn ọlọpaa kede pe Raṣidi lo ṣeku pa akẹkọọ ẹka ifowopamọ ati iṣuna (Banking and Finance) ni Poli Ẹdẹ, lasiko ti iyẹn waa gba lẹta fun isinru ilu rẹ.

Bakan naa ni wọn lo tun pa ọlọkada kan lasiko ti aawọ kan bẹ silẹ niluu Ẹdẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ọmọkunrin ọhun ti n ran ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn.

Leave a Reply