Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ile-ẹjọ Magistreeti kan niluu Ilọrin, ti paṣẹ ki wọn sọ baale ile kan, Usman Baba, ẹni ogoji ọdun, sẹwọn, fẹsun pe o fi ṣeeni so iyawo ile kan, Arabinrin Aishat Ibrahim, mọlẹ fun odidi ọsẹ meji gbako, o ni ajẹ ni.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, lo wọ Usman Baba lọ siwaju ile-ẹjọ fẹsun pe oun pẹlu iyawo rẹ gbimọ-pọ so iyawo ile kan, Arabinrin Aishat Ibrahim, mọlẹ fun odidi oṣu meji, ti wọn ni ajẹ ni. Awọn agbofinro tẹsiwaju pe tọkọ-taya yii gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira lọwọ mọlẹbi rẹ gẹgẹ bii owo itusilẹ ki wọn too fa a le awọn mọlẹbi lọwọ.
Agbefọba, Zacchaeus Fọlọrunshọ, rọ ile-ẹjọ ko fi afurasi naa pamọ sọgba ẹwọn tori pe iwa ọdaran paraku lo hu.
Onidaajọ Ibrahim Dasuki paṣẹ pe ki afurasi naa lọọ maa gba atẹgun lọgba ẹwọn, o sun igbẹjọ si ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.