Awọn agbebọn pa Tajudeen atọmọ rẹ siwaju ṣọọbu iyawo rẹ l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ere aṣapajude lawọn ọlọja atawọn ti wọn n kọja lagbegbe Okeejẹtu, ni Garaaji Ileṣa, niluu Oṣogbo, sa lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, nigba ti awọn agbebọn ti ko sẹni to mọye wọn yinbọn mọ ọkunrin kan, Tajudeen, ti inagijẹ rẹ n jẹ Spanner, latori ọkada. Ọmọkunrin yii ni wọn ni o mu ọkan lara awọn ọmọ rẹ lọwọ, to si fẹẹ ra nnkan ni ṣọọbu iya alatẹ kan nibẹ.

Nibẹ ni wọn ti yinbọn fun ọkunrin ẹni ọdun marunlelogoji yii leralera latẹyin, nigba ti wọn si ri i pe o ti jade laye ni wọn too kuro nibẹ.

ALAROYE gbọ pe ọta ibọn ba ọmọdebinrin rẹ to mu lọwọ, nigba ti awọn ti wọn wa lagbegbe yoo si fi gbe e deleewosan, ọmọ naa jade laye.

Ọkan lara awọn paaki NURTW ti isọ Eko to wa loju-ọna Gbọngan si Oṣogbo, la gbọ pe Taju ti n gbero, bẹẹ lo si tun ni ṣọọbu ti wọn ti n gẹrun ninu Oṣogbo.

Agbẹnusọ awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ nipa iṣẹlẹ naa. O ni bi awọn kan ṣe fi to ileeṣẹ naa leti ni nnkan bii aago kan ọsan ku iṣẹju mẹẹẹdogun lawọn ti lọ sibẹ, ṣugbọn oku Tajudeen lawọn ba.

Ọpalọla ni, “A gbọ pe afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun lọmọkunrin naa, iwaaju ṣọọbu iyawo rẹ ni wọn si pa a si lagbegbe Garaaji Ileṣa, niluu Oṣogbo”

Leave a Reply