‘Lori ọrọ eto aabo, ẹ jẹ ki Buhari lọọ sinmi sile’

Monisọla Saka

Alaṣẹ ileeṣẹ redio RadioNow, Kadaria Ahmed, ti sọ pe ti Aarẹ Muhammadu Buhari ba mọ pe awọ oun o kaju ilu ọrọ eto aabo mọ, to si mọ pe ipa oun ti pin, ko lọọ sinmi sile, ko si fun ẹlomi-in laaye ati maa tukọ orilẹ-ede yii.

Ahmed to ṣapejuwe irinajo ileeṣẹ iroyin BBC lọ sọdọ awọn agbebọn nipinlẹ Zamfara gẹgẹ bii iroyin ti ko mọgbọn wa sọ eleyii di mimọ lasiko to n ba ileeṣẹ tẹlifiṣan Arise TV sọrọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

O ni wọn le fẹsun riran awọn agbesunmọmi kan ileeṣẹ BBC Africa, nitori wọn gbe awọn ẹni ibi yii gẹgẹ faye ri nipa fifun awọn apanijaye ẹda yii lanfaani lati fi ero ati iwa ika wọn han si awọn to ti ko si panpẹ wọn atawọn ti wọn n han leemọ.

Obinrin agba ọjẹ oniroyin yii waa ni oun ko ri ohun to le mu ki Aarẹ ma ṣe ojuṣe ẹ lati daabobo ẹmi ati dukia awọn eeyan ilẹ yii.

O ni Buhari kuku ti sọ tẹlẹ pe ko si orilẹ-ede kankan to le da nikan ṣẹgun awọn agbesunmọmi, leyii to tumọ si pe ko sohun to le ṣe lati daabo bo ilẹ yii.

“Ara rẹ ko ya latigba yii wa, boya ko lọọ sinmi sile fun gbedeke igba kan, ko si faaye gba ẹlomi-in lati maa baṣẹ lọ. Nitori oun funra ẹ ti juwọ silẹ, o ni ko si orilẹ-ede to le da nikan rẹyin awọn agbebọn ati agbesunmọmi.

“Ohun ti mo n gbọ ni pe, ‘Ko da mi loju pe nnkan mi-in wa ti mo tun le ṣe’. Ohun ti mo gbọ to sọ niyẹn. Boya akoko ti waa to bayii lati wa wọrọkọ fi ṣada”.

Leave a Reply