Gbenga Amos, Ogun
Ọṣẹ buruku tawọn agbebọn afẹmiṣofo gun le nilẹ Yoruba ti bẹrẹ si i ro gbọnmọ-gbọnmọ bayii, o si yẹ ki awọn gomina ilẹ Yoruba ati gbogbo awọn alẹnulọrọ wa nnkan ṣe si i ko too buru ju bayii lọ.
Ọsẹ kan lẹyin iwa ika ti wọn hu l’Ogbomọṣọ, nibi ti wọn ti pa olotẹẹli kan ati ọmọọṣẹ rẹ pẹlu ọlọkada to gbe ẹni to lọọ gbe owo fun wọn, awọn ẹni ibi yii tun ya wọ otẹẹli Garden of Comfort, to wa lagbegbe Ṣoyọye, loju ọna to lọ lati Lafẹnwa si Rounder, nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, wọn yinbọn pa ẹṣọ alaabo So-Safe kan, Ọgbẹni Ọlanrewaju Shofọlahan, wọn si ji obinrin kan gbe lọ.
Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o waye ni nnkan bii aago mẹwaa ku iṣẹju mẹwaa alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ yii, wọn lawọn afurasi Fulani agbebọn lo ṣiṣẹ ọhun.
Alukoro fun ajọ ẹṣọ alaabo So-Safe nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Moruf Yusuf, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ ninu atẹjade kan lọjọ Aje, Mọnde yii, o ni bawọn agbebọn naa ṣe fẹẹ ji obinrin ọhun gbe niwaju Garden of Comfort to wa nibudokọ to kẹyin, ni Ṣoyọye, l’Abẹokuta, ẹṣọ alaabo naa ṣapa lati kan si awọn agbofinro mi-in ki wọn le waa ṣeranwọ, ibẹ ni wọn ti yinbọn fun un, ti wọn si da ẹmi ẹ legbodo.
A gbọ p’awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii, lati tọpasẹ awọn ẹni ibi ọdaran naa, ki wọn le doola ẹmi obinrin ti wọn ji gbe ọhun.
Ọga agba ajọ So-Safe nipinlẹ Ogun, Kọmandaati Sọji Ganzallo, sọ pe gbara toun gbọ nipa iṣẹlẹ naa loun ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ oun to wa ni ẹka ti Ẹgba, pe ki wọn lọ sibẹ, ki wọn si ro aabo agbegbe naa lagbara, ki wọn tọpasẹ awọn olubi naa, ki wọn si wa wọn lawaari.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ko ti i gbe aago rẹ lati sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun.