Igbẹjọ yoo bẹrẹ lori ẹsun ayederu iwe-ẹri ti wọn ni Tinubu n ko kiri

Faith Adebọla, Eko

 Ile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, ti pinnu pe igbẹjọ maa bẹrẹ lọjọ keje, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, lori ẹsun ti wọn fi kan oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, pe o yiwee-ẹri, ayederu lawọn sabukeeti to n ko kiri, ati pe ko kun oju oṣuwọn lati dupo aarẹ pẹlu awọn iwe-ẹri naa.

Awọn eekan eekan mẹrin ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn wa lara awọn aṣoju to kopa ninu eto idibo abẹle apapọ, nibi ti APC ti fa Tinubu kalẹ loṣu Kẹfa, ọdun yii, ni wọn wọ Tinubu lọ si ile-ẹjọ. Awọn mẹrin ọhun ni Memuna Suleiman, Jigo Garba, Ofodu Anthony ati Ibiang Ibiang.

Yatọ si pe igbẹjọ naa yoo waye, Adajọ Ahmed Mohammed tun paṣẹ pe ki wọn lo gbogbo ọna to ba ṣi silẹ lati ri i pe iwe ipẹjọ naa tẹ Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu rẹ lọwọ ko too di ọjọ naa, o ni ti ko ba ṣee ṣe lati fun un lojukoroju, ki wọn lẹ ẹ mọ ẹnu ọna ile rẹ, tabi ki wọn gbe iwe-ipẹjọ naa soju iweeroyin atigbadegba, ki awọn olujẹjọ naa ka a nibẹ, latari ẹsun tawọn olupẹjọ naa fi kan Tinubu pe niṣe lo n sa, ti ko fẹẹ gba a lọwọ awọn.

Bakan naa ni wọn to orukọ ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ileegbimọ aṣofin, ati minisita feto idajọ, mọ awọn olujẹjọ lori ẹsun ọhun.

Awọn olupẹjọ yii rọ ile-ẹjọ lati wọgi le orukọ Tinubu kuro lara awọn oludije ti yoo kopa ninu eto idibo aarẹ lasiko idibo gbogbogboo ọdun 2023.

Wọn fẹsun kan Tinubu pe opurọ ẹda ni, wọn ni awọn iwe-ẹri agbelẹrọ, ti ko muna doko, lo fi ṣẹri ara ẹ ni ninu fọọmu idije funpo aarẹ to fi ṣọwọ si ajọ eleto idibo, INEC.

Leave a Reply