Monisọla Saka, Eko
Oṣiṣẹ ileewe giga poli ijọba apapọ to wa ni Idah, nipinlẹ Kogi, ni ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ naa ti tẹ bayii lẹyin to ji ọmọ bibi inu ẹ, obinrin ọmọ ọdun mẹẹẹdogun gbe, to si tun pada ṣeku pa a.
Awọn ọlọpaa tun fi panpẹ ofin gbe ọrẹ baba ọmọ yii toun naa jẹ oṣiṣẹ nileewe giga yii kan naa gẹgẹ bii alajọṣiṣẹpọ iwa ọdaran yii.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, William Ovye-Aya, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ ṣalaye pe, Sherrifah to jẹ ọmọ oṣiṣẹ poli yii ni wọn ji gbe lọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ, ọdun ta a wa yii nile wọn to wa ni Okenya, lagbegbe Itayi, nijọba ibilẹ Igalamela/Odolu, nipinlẹ Kogi.
Lẹyin ọjọ bii meloo kan ti wọn ti n wa a pẹlu ọpọlọpọ idaamu ni wọn ri oku ẹ, ṣugbọn ti ko pe mọ, wọn ti yọ awọn ẹya ara rẹ kan lara ẹ, ki wọn too ju u sibi ti wọn ti ba oku ẹ.
Aya tun tẹsiwaju pe, awọn tun n wa afurasi ọdaran mi-in. Afurasi yii lagbẹnusọ awọn ọlọpaa ni oun naa n ṣiṣẹ nileewe giga Poli Idah.
Alukoro ọlọpaa ṣalaye pe, “Ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, ni wọn ni wọn ji Sherrifah gbe nile wọn to wa ni Okenya, agbegbe Itayi, nijọba ibilẹ Igalamela/Odolu, nipinlẹ yii kan naa.
“Ọjọ meloo kan lẹyin ti wọn ji i gbe ni wọn ri oku ẹ, ti wọn ti ge awọn ẹya ara ẹ lọ”.
Ovye-Aya fi kun un pe iwadii ti bẹrẹ, bẹẹ lawọn n ṣakitiyan lati mu afurasi kẹta ti wọn pe orukọ ẹ ni Adah.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Edward Egbuka, ti paṣẹ pe ki wọn ṣe iwadii to lọọrin lori ọrọ naa, ki wọn si ri i daju pe ọwọ wọn tete ba Adah.