Baba atọmọ ku sibi ti wọn ti n ko kanga

Monisọla Saka, Eko

 

Baba agbalagba ẹni ọgọta ọdun kan, Malam Bala, ati ọmọ ẹ, Sanusi Bala, to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji (35) ti ku sinu kanga kan ni Sabon Garin Bauchi, nijọba ibilẹ Wudil, nipinlẹ Kano.

Kanga lawọn oloogbe mejeeji n ko lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.

Agbẹnusọ ileeṣẹ panapana nipinlẹ ọhun, Saminu Abdullahi, to fọrọ ọhun lede ninu atẹjade ṣalaye pe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, niṣẹlẹ ọhun waye.

 

 

 

O ni, “A gba ipe pajawiri lati ileeṣẹ panapana Wudil, ni nnkan bii aago mọkanla aabọ aarọ, latọdọ ẹni kan to pe ara ẹ ni Isma’ila Idris, pe awọn meji kan ti ko si kanga, wọn o si rọna jade.

Lojuẹsẹ naa la ti ran awọn ikọ wa lọ si agbegbe iṣẹlẹ naa ni nnkan bii aago mọkanla aabọ kọja iṣẹju mẹta.

“Nigba tawọn oṣiṣẹ panapana debẹ ni wọn ri i pe iṣẹ kanga kiko ni wọn bẹ baba atọmọ naa, ti wọn si ṣe e daadaa.

Ọmọ baba yii lo wo o pe awọn o ti i ko o daadaa to, lo ba pada lati tubọ tun inu ibẹ ṣe, nibẹ lo si wa ti ko jade sita mọ.

 

 

“Lẹyin ti baba woye pe o yẹ ko ti ṣetan ko jade ti ko si ri ọmọ ẹ ni ara abiyamọ ta a, loun naa ba ko sibẹ lati doola ẹmi ọmọ ẹ, ṣugbọn gẹgẹ bi ọmọ ẹ naa, oun naa wọle, atijade pada dogun nigba ti oun naa gbẹmii mi latari aisi atẹgun to ṣe e mi simu ninu kanga naa”.

Ileeṣẹ panapana ṣalaye siwaju si i pe baba atọmọ naa o mira, bo ti wu ko mọ nigba ti wọn gbe wọn jade, lẹyin naa ni wọn sọ ọ di mimọ pe awọn mejeeji ti jẹ Ọlọrun nipe.

Leave a Reply