Lasiko tawọn obi wọn lọ si ṣọọṣi, ibeji kan pokunso l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ojiji kan to waye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹjọ yii, l’Ekoo. Ọmọọdun mẹrinlelogun kan, Clinton Azubuike, ni ekeji rẹ ti wọn jọ jẹ ibeji ṣadeede ba lori okun to so mọ faanu wọn, to n fi dirodiro, o ti pokunso, o si ti ku.

Ile awọn obi ọmọ naa to wa ni Banana Island, lagbegbe Ikoyi, l’Erekuṣu Eko lọhun-un, niṣẹlẹ ibanujẹ naa ti waye. Ọdọ awọn obi Taye-Kẹhinde naa ni wọn n gbe.

 

Wọn ni ko sẹni to fura pe iru iṣẹlẹ yii fẹẹ waye, tori titi di owurọ Ọjọ Isinmi ọhun, awọn ibeji yii ṣi jọọ sọrọ, kawọn obi wọn too lọ si ṣọọṣi, ko si si ami pe nnkan kan n ṣe Clinton rara.

Ohun ta a gbọ ni pe ni nnkan bii aago mọkanla owurọ tawọn obi wọn ṣi n ṣe ijọsin lọwọ, ti ekeji rẹ ti wọn jọ wa nile ko si nitosi, oloogbe yii pojobo okun, o so o mọ faanu to wa loke yara alejo, o si ti ọrun ara rẹ bọ okun naa, lo ba pokunso.

 

Ekeji oloogbe yii ti wọn jọ jẹ ibeji lo ṣadeede wọ yara igbalejo naa, iyalẹnu ni bo ṣe ri Clinton to n fi dirodiro loke, lọmọ naa ba figbe ta sawọn aladuugbo, bo tilẹ jẹ pe fulaati ni ile wọn, o to ile kẹta ko too rẹni ran an lọwọ.

Wọn yọ Clinton lori okun, wọn si sare gbe e digbadigba lọ sileewosan First Cardiologist, lati doola ẹmi ẹ, wọn lo ṣi n mi diẹ diẹ, ṣugbọn awọn alaṣẹ ileewosan naa ni ki wọn ma ṣafira, ki wọn tete maa gbe e lọ si sileewosan ẹkọṣẹ iṣẹgun Fasiti Eko, Lagos State University Teaching Hospital (LASUTH).

 

Nigba ti wọn yoo fi de LASUTH to wa n’Ikẹja, l’Ekoo, ẹpa ko boro mọ, wọn lọmọkunrin naa ti dagbere faye, o ti ku patapata.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni wọn ti gbe oku oloogbe naa lọ si mọṣuari fun ayẹwo lati mọ ohun to ṣatọna si iku ojiji yii, ayẹwo naa lo maa jẹ ki wọn mọ igbesẹ to kan.

Leave a Reply