Awọn agbebọn pa oludasilẹ Otẹẹli 16 Hour, wọn ji ọrẹ ẹ gbe lọ ni Kwara

Awọn agbebọn ti wọn dihamọra pẹlu ibọn ati ohun ija oloro miiran ni wọn ya bo otẹẹli kan ti orukọ rẹ n jẹ 16 Hour, lagbegbe Alomilaya, Ganmọ, Ilrin, nipinlẹ Kwara, ti wọn si n yinbọn leralera.

 

Nibẹ ni wọn ti yinbọn pa oludasilẹ otẹẹli naa, Kayọde Akinyẹmi, ẹni ọdun mẹtadinlaaadọrin. Manija rẹ, Emmanuel Olushila Ojo, fara gbọta ibọn ni tiẹ, wọn si ji ọrẹ rẹ kan ti wọn n pe ni Ori gbe sa lọ.

 

 

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lọjọ Aje, Mnde, ọsẹ yii, lo ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si sọ pe alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ni iṣẹlẹ naa waye. O ni manija to fara gbọta ibọn ti n gba itọju to peye nileewọsan Jẹnẹra tilu Ilọrin, ti ileeṣẹ ọlọpaa si ti ko awọn ẹsọ alaabo lọ si agbegbe naa lati wa awọn afurasi ọhun lawaari, ki wọn si doola ẹmẹni ti wọn ji gbe lọ.

 

 

Kọmianna ọlọpaa ni Kwara, CP Tuesday  psc(+), ti fofin de lilọ-bibọ awọn eeyan lagbegbe naa ki awọn ọlọpaa le raaye iẹ wọn, ki wọn le mu awọn afurasi ọdaran naa.

 

Leave a Reply