Wọn ti mu Emmanuel to n ji eroja ẹrọ ibanisọrọ kiri l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 

Pako pako bii maaluu to rọbẹ, lọkunrin afurasi ọdaran kan torukọ rẹ n je Emmanuel Aarọn, ẹni ọdun marundinlogoji, yii n wo, nigba tọwọ awọn agbofinro tẹ ẹ lagbegbe Mẹiran, nipinlẹ Eko, nibi to ti n jale, o n tu ẹya ara ati eroja ẹrọ ibaniṣọrọ ti wọn ri mọlẹ, o n ta wọn.

 

 

Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣe ọlọpaa ṣe sọ f’Alaroye ninu atẹjade kan lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, SP Benjamin Hundeyin sọ pe lọjọ Tọsidee to kọja, ni nnkan bii aago mẹta kọja iṣẹju marun-un, lọganjọ oru, tọwọ ti pa, tẹsẹ ti pa, ni wọn lọkunrin bẹrẹ iṣẹẹbi rẹ, o ja kọkọrọ ti wọn fi tilẹkun ile ti wọn ri ẹrọ ibanisọrọ giriwo naa mọlẹ si laduugbo Isoto, ni Mẹiran, o yọ irinṣẹ ti wọn fi n tu ẹya ara ọkọ, o bẹrẹ si i tu awọn eroja kinni naa, lawọn kan ti wọn kẹẹfin rẹ ba dọgbọn ta ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lolobo lori aago wọn.

 

 

Wara-were lawọn ọlọpaa ti lọ sibi ti wọn juwe pe afurasi naa wa, bi wọn si ṣe sọ ọ ni wọn ba a loootọ, wọn ka a mọnu ọgba ẹrọ ibanisọrọ kan, o ti ji awọn eroja kan tu silẹ, o n tu omi-in lọwọ ni wọn debẹ.

 

 

Wọn ni bo ṣe ri wọn lo fẹẹ sa lọ, o gbiyanju lati gun fẹnsi ọgba naa, ṣugbọn ko ṣee ṣe, ni wọn ba mu un.

Ki i ṣe ọkunrin yii nikan lo waa jale ọhun, awọn ẹlẹgbẹ rẹ kan wa nitosi rẹ, ti wọn n ba a ko awọn eroja to ji tu naa lọ sinu mọto Ford kan ti wọn gbe sẹgbẹẹ ọna, nitosi ibẹ, nọmba ọkọ naa ni FKJ519YF, ṣugbọn bi awọn eleyii ṣe kẹẹfin awọn ọlọpaa, niṣe ni wọn poora bii iso, wọn sa lọ.

 

 

Ṣugbọn wọn ko ri ọkọ naa gbe lọ, nigba tawọn ọlọpaa si yẹ inu mọto wo, wọn ba oriṣiiriṣii ẹru ole atawọn eroja ibanisọrọ rẹpẹtẹ ti wọn ji tu.

Bi Hundeyin ṣe wi, wọn ti n ba iṣẹ iwadii lọ lori iṣẹlẹ yii, wọn si ti fi Emmanuel ṣọwọ si ẹka to n ri si iwa idigunjale lọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, fun iṣẹ iwadii.

 

 

O ni awọn agbofinro ṣi n dọdẹ awọn afurasi ole ti wọn sa lọ, ki wọn le foju gbogbo wọn bale-ẹjọ lẹyin iwadii.

Leave a Reply