Ibrahim Alagunmu
L’Ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, ni wọn lu onikẹkẹ Maruwa kan ti ko sẹni to mọ orukọ rẹ lalubami l’Opopona Sawmill si Geri-Alimi, niluu Ilọrin, fẹsun pe o ji foonu ero to gbe sa lọ.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ni iṣẹlẹ naa waye, nibi ti onikẹkẹ Maruwa ti nọmba rẹ jẹ Kwara, PTG 694 UZ, ti gbe ero lati Geri-Alimi, to n lọ si Sawmill, niluu Ilọrin, sugbọn ti onikẹkẹ sadeede duro lojiji, to si sọ pe kẹkẹ ti bajẹ, ki ero naa sọkalẹ, oun fẹẹ tun un ṣe, laimọ pe ọkunrin to jokoo ti i ti yọ foonu rẹ, Ero naa sọ pe lẹyin toun fura pe foonu oun ti sọnu ni onikẹkẹ Maruwa naa n sa lọ, toun ko si ri ẹni toun jokoo ti ninu kẹkẹ mọ, ọmọkunrin naa loun fi ọkada le e, ọwọ si tẹ ẹ ni agbegbe Sawmill.
Nigba ti wọn lu u daadaa lo jẹwọ pe iṣẹ foonu jiji ni awọn yan laayo, ati pe ẹni keji to bọọlẹ, awọn jọ n ṣiṣẹ papọ ni.
Wọn ti gba kẹkẹ rẹ, wọn si ti fa a le ọlọpaa lọwọ.