Agbarijọpo ẹgbẹ oṣelu ṣatilẹyin fun idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Agbarijọpọ ẹgbẹ oṣelu lorileede yii, ẹka tipinlẹ Ọṣun, Inter-Party Advisory Council (IPAC) ti sọ pe awọn ti wa nigbaaradi fun eto idibo ijọba ibilẹ ti ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọṣun, OSIEC, fẹẹ ṣe.

 

Laipẹ yii ni OSIEC kede ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, gẹgẹ bii ọjọ ti eto idibo yoo waye sijọba ibilẹ ọgbọn, ijọba agbegbe mejilelọgbọn ati eeria ọfiisi meje.

Ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu PDP fariga, wọn ni eto idibo naa ko bofin mu, wọn ni ki ni ẹgbẹ oṣelu APC n wo lati ọdun mejila ti wọn ko ṣeto idibo, to waa jẹ pe lẹyin ti wọn lule ninu idibo gomina ni wọn sare fẹẹ ṣeto idibo ijọba ibilẹ.

Ṣugbọn IPAC, ninu ipade oniroyin ti wọn ṣe, nibi ti awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu mẹrindinlogun ti peju, ṣalaye pe ọrọ idagbasoke ẹsẹkuuku yẹ ko lagbara lọkan awọn ẹgbẹ oṣelu ju ọrọ oṣelu lọ.

Ninu akọsilẹ ti alaga wọn, to tun jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu APM, Ọnarebu Adebayọ, ka, ni wọn ti sọ pe awọn ti ṣetan lati kopa ninu idibo naa nitori awọn mọ pe ijọba ibilẹ lo sun mọ araalu ju, ibẹ si ni iṣẹ idagbasoke ti tete maa n farahan.

Wọn ke si awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati tu jade lọjọ idibo naa gẹgẹ bii ipinlẹ Ọmọluabi ti wọn mọ ipinlẹ Ọṣun mọ, ki wọn si dibo fun alaga ati kanselọ ti wọn ba fẹ.

O ni ninu ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to wa nipinlẹ Ọṣun, mẹrindinlogun ni wọn ti fi ifẹ han lati kopa ninu idibo naa, bẹẹ ni awọn ko si mọ idi ti ẹgbẹ oṣelu PDP ati APP fi pinnu pe awọn ko ni i kopa ninu idibo ọhun.

IPAC ke si ajọ OSIEC lati ri i pe eto idibo naa lọ nibaamu pẹlu alakalẹ eto idibo, ti ko si gbọdọ ni kọnu-n-kọhọ kankan ninu.

Leave a Reply