Ibrahim Alagunmu
Akolo ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ni gende ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Ibrahim Hassan, wa bayii, latari bo ṣe ṣeku pa baba rẹ, Alagba Sabi Ibrahim, ẹni aadọrun-un ọdun to jẹ ajagun-fẹyinti.
Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, sọ pe lọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 yii, ni arabinrin kan, Aishat Ibrahim, mu ẹsun wa pe ṣadeede ni baba awọn dawati laduugbo Ajibẹsin, Ogidi, lagbegbe Oko-Olowo, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara. O ni gbogbo ibi tawọn le wa a si lawọn ti de, ṣugbọn awọn ko ri i, eyi lo mu kawọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lẹsẹkẹsẹ.
Ko pẹ lẹyin naa ni wọn mu afurasi ọdaran yii, Ibrahim Hassan.
Lasiko iwadii ni Hassan jẹwọ pe kawọn ọlọpaa ṣe oun jẹẹjẹ, oun loun pa baba oun, o ni niṣe loun kọkọ po parasitamọọ atawọn eroja kan pọ, toun fi gun baba oun abẹrẹ, eyi to mu ki ooyi kọ ọ, ti ko si lagbara mọ, loun ba tọrọ ọkada ọrẹ oun kan, oun si fi gbe e lọ si banki WEMA rẹ lati paarọ kaadi to fi n gbowo lẹnu ẹrọ, iyẹn kaadi ATM rẹ si tuntun, eyi si jẹ koun mọ nọmba aṣiiri kaadi tuntun naa, iyẹn pin nọmba rẹ.
O jẹwọ pe nigba tawọn n dari bọ loun gbe baba naa lọ sibi ile akọku kan, toun si pa a, loun ba gbẹ koto kuṣẹkuṣẹ kan, oun si bo baba naa mọlẹ sibẹ.
Lẹyin eyi n’Ibrahim kọri si ilu Kaduna, o bẹrẹ si i fi kaadi naa gba owo jade lakaunti oloogbe ọhun, tori akaunti yẹn ni wọn n sanwo ifẹyinti ati ajẹmọnu baba naa si. Bakan naa lo ta ọkada ẹni-ẹlẹni ni gbanjo, o si bẹrẹ si i jaye ori ẹ lọhun-un.
Ibrahim ni gbogbo owo toun ṣi gba ko ju ẹgbẹrun lọna mọkandinlaaadọta Naira (N59,000) kọwọ too tẹ oun ni Kaduna, ti wọn si da a pada si Kwara. O ni tori koun le maa lo kaadi ATM baba oun loun ṣe pa a danu, nigba toun kuku ti mọ nọmba aṣiri kaadi naa.
Ṣa, Alukoro ọlọpaa ni awọn ti gba kaadi ATM naa, awọn si ti ri ọkada to gbe sa lọ gba pada. Laipẹ ni wọn yoo foju ole ati apaayan yii bale-ẹjọ.